Ogun abiku

OGUN ABIKU

1. Iyẹ adiẹ dudu, ewe abirikolo, eku asin kan, ọga kan, ẹgusi ti wọn ba ṣẹ silẹ ni ilẹ ọja ati ireke ti wọn ba jẹ silẹ ọja, ao jo gbogbo rẹ pọ, a fi sinu adi, a ma la, a si ma fi para!


2. Ila tí o ko lori iya rẹ, ikan ti o ba gbo sori
iya rẹ, ewe ayunrẹ-bọnnabọnna, yimiyimi ati imi rẹ na, ao jo gbogbo rẹ pọ, ni ọjọ ti a ba bi ọmọ na. ki a to da iwọ rẹ, a kọ sin ni gbẹrẹ meji lori, meji laiya, meji leyin, baba ọmọ yio sin mẹta laiya. ati iya ọmọ naa, lẹhinna wọn o wa da iwọ ọmọ na

3. Ewe apa 200, Ewe aro 200, Obi Ifin oloju 4, Obi ipa oloju 4, ao ko gbogbo re le ori ibi omo naa ninu isasun, A wa gbẹ ile kotokoto ninu aro ti a bati nda ina ni ojojumo A wa ri isasun yi mobe, ni ọjọ 7, a wa wu ibi omo yi, gbogbo ewe ti o wa ni ori re ni awalo,a wa da adi eyan si, won o ma fi pa omo na lara, won o si ma to si ni enu.

4. Eku asin 2, Oga 2, Tangiri, Igi taba, Ao jo gbogbo re po, Epo, Ori, Adi, Ama to fun obinrin ti o loyun yi, nigbati o ba si bimo won o si ma to si omo lenu.

5. Ewe-egungun ọrun, ao lọ, yio fi si adi yioma fi pa omu titi de ejika, nigbati o ba ni oyun ninu.

6. Omi elubo isu gidi, ki se elubo lafun o, ewe taba tutu, aose yio jinna dada, nigbati o ba jinna tan, ao ro sinu igo pelu adi, omo na yio ma mu, yio sima fi ra ara, tabi nigbati oyun re wa ni ikun iya rẹ yio ma mu.

7. Isasun tuntun, ewe-jenjoko 200, ewe alupayida 200, ewe ọwọ koniye, Obi-Ifin kan, a se si 200, Obi Ipa kan ase On na si 200, bi o ba se obirin abo adie, a tu huhu re, adie na ko si gbodo ku, bi o ba se okunrin, akuko adie ase bakanna, a wako le ori ibi omo ti nbe ninu isasun, nigbati adie yi ba hu iye, a wa fi se sara fun. enikan, a wa lo sin ibi omo na sinu oko kan, ao lo peregun ati ọgẹdẹ le lori.

8. Alabahun kan, Igbin kan, ewe iyeye, Isawiri 16, Obi Ipa kan, Obi Ifin kan, Alangba kan, Ao jo gbogbo rẹ po, Ao tẹ ni ejiogbe, Ao da ogun yi si meta, Won o fiida kan re gun ose, Ida kan yoku won o fun Iya omo yio ma fi fo oko mu, Ida keta ni ọjọ ti won ba bi ọmọ na, won yi o da yoku si ori ibiomo na, won yio si lo re sin si baluwe.

Ofo re: -Orun mọ laro, Orun mọ laro, Mọro, o difa fun Oduduwa atẹwon rọ to ma ko tulasi ba obalufon sun, Obalufon, setan Obi ipa, Obi ẹgba, Obi idayin, Obi orẹrẹ, ejiogbe, ni ko ni bi pa mọ, ko ni bi orẹrẹ mọ, ko ni bi ẹgba mọn, ko ni bi idayin, oba lufon, setan obi ipa, obi egba, obi idayin, obi orere ejiogbe ni ko ni bi pa mo, ko ni bi orẹrẹ mo, ko ni bi egba mo, ko ni bi idayin.