Ogun Ọsẹ Iwebi

OGUN OSE IWEBI

1. Ogun yi dara pupo fun eniti oba loyun, titi ti aboyun yio fi bimo ko ni si iyolenu fun obirin naa ni agbara Olorun

Eso isin, ata were pupa, odidi atare kan, ao jo gbogbo rẹ pọ, ao ma ta epo ori aro, meteta ao gun mo ọsẹ obirin na yio ma fi we toritori.

2. Ewe-Abiwere, a gun mo ọṣẹ ẹta, a wa ra ose bia mu dele, a wa ko eta le lori, bebere igbin, a wa gun, a ma fi we toritori ni osu kesan (9).

3. (Agbo) Epo ahun, ao pa yio po, mu ororo eyin adie kan tẹlẹ ikoko, ao se, nigbati o ba tutu, obirin yi yio mu eyin adiẹ yi yio jẹ, yio da omi yi sinu igba kan, yio wa gbe lo si akitan ni oru yio wa da omi na Sori lekanna.

4. Ewe lapalapa, ao ko sinu ape,a fi eyin adie kan si, ẹẹru awonka, ao se gbogbo rẹ pọ, yio je eyin yi, yiowa da omi yi si ori ni alẹ

5. Ewe pandoro a fi owu dudu ati funfun di si mesan (9), A ma fi eru alamo kokan si, Roro ogede weere, a di si mesan (9), a tun fi eru alamo kokan si, a fi imi ti a ba ri ni akitan tele ikoko ati eyin adie kan ati ẹẹru, a wa se dada yio mu adie jẹ, yio wa fiomi agbo we ni ita ni ale

6. (Ayobi) Eso orun ewure, ila kan, pẹpẹ ni afi rẹ ila yi, iyere ni ata re a wa se, ‘obirin na yio ma je.