Asogbo; Ogun bi oyun ba n baje lara Obinrin

ASOGBO

Ohun ti a pe ni Asogbo ni wipe ki oyun ki o ba jẹ lara obinrin ni osu meta tabi mefa, tabi meje, tabi merin, eleyi ni a pe ni asogbo o.

1. Orombo wẹẹrẹ lọpọlọpọ, Okusu aro, a o fun eso bonni, a wa toju sukusuku ọgẹdẹ wẹwẹ, kanhun diẹ, a wajo, obinrin na yio ma fi fo eko tutu mu.

2. Igbin kan, ayo ni tutu sinu isasun, ewe dede-kunde, ewe-rinrin, ewe etigbure, ata wewe, epo, Ori, isasun tuntun la fi se obe na, obe na dara fun oyun ti o ba nbu, yio maje ni emeta lojumọ

3. Igbin kan, Apopo obi gidi, a o gun pelu kanhun, ata, alubosa, Iyere, obuotoyo, yio ma fi mu eko gbigbona, nigbati a ba gun tan. Agunmu yi dara fun awon aboyun, ti o ba nsu igbẹ asule.

4. Igbin kan, awọn ode, a si npe awon ode yi ni ewe aiku, ao jo po, eko fifo mu ni araro.

5. Igbin kan, Eja abori, eso ibepe, Odidi atare meta, a o jo po, yio ma fi fo eko mu.

6. Ogede were ti ko ba ti gbo, ewe-odundun, ewe rinrin, ewe-abamoda, ewe-alupayida, eso-kerewu, Irun osa, a o Jo gbogbo rẹ pọ, eko si ni ama fi fo mu ni emeta lojojumo.

7. Egbo peregun, Egbo atori, Egbo Itakun okẹrẹ, ewe-etiponola, ao se ni agbo, yio ma we, yio si ma mu, lati osu keji ti o ba ti loyun yi ni a ti se agbo yi o

8. Egbo toto, Egbo awusako, Epa ikun, Ojuoro, ewe oruwo, Egbo ope, ao se dada, yio ma mu, yio si ma fi we pelu, titi di osu mesan (9 months).