OGUN Bi OYUN BA NBU

OGUN BI OYUN BA NBU

Ogun dada ni ogun na je, bi oyun ba mbu, bi a ba lo ogun yi, ni agbara Olorun, Oyun na ko ni bu mon

1. Iye eiyele, panti aroti agbara, Odidi atare kan, Ewe-alupayida, A o jo gbogbo re po, yio ma fifo eko tutu mu

2: Ao mu eko lo sidi odan ẹki, ao ko oje-odan si ekọ na, Oje na si gbodo dun eko na dada, yi o wa fo eko na mu, ni ẹẹmeta ni ojumo.

3.Igbin kan, Ogede were pipon, rinrin, odundun, lyere, Iyo. A gun gbogbo re po, a wa sa si ehin Igba, nigbati o ba da eko kalẹ yi oju koko ori kan si, yio wa bu Ogun yisi ki o to mu eko na.

4. Aso waji, Ewe alupayida opolopo, iyere, atare kan, ao jo gbogbo re pọ, yio ma fi fọ ẹkọ tutu mu.

5. Eso lara pupa, owo-eyo 40, Irẹ 10, eso ido lopo- lopo, ao jo gbogbo repo mo ara won, afi odidi atare-kan kun, A ma fi fo eko tutu mu.

6. Asa ọgẹdẹ wẹẹre ti yio gbe ni ọjọ naa, a wa lo yio kunna, omunu ewe òrúwọ a o lo po mo iyere, alubosa, emo agbo, ao lọ yio kunna dada, Epo, Ori, Adi, A si toju isasun tuntun a wa ko gbogbo ogun yi sinu isasun na, a wa se jinna, nigbati a baso kale niawa ku ogede ti alo yi si, kia toso, A gba aso obirin yi, asu ni osuka, asi toju abọ owu, a te leri aso ti asu ni osuka yi, la wa so isasun yi ka, a wa de, obirin yi yio ma je

7. Ile ọde ti idi re mon ara ile, odidi atare kan, akuro alantakun, aa ja ko ni kan ile, a wa lo, obirin na yio ma fifo eko mu.

8. Ao mu eyo atare 10, ao mu lo si idi egbo jenjoko, nigbati a ba wa egbo jenkoto yi tan, a wa da eyo atare 10 yi sinu koto re, awa lo egbo yi, a wa mu eyin adie kan, arora da eyin yi luni ori, omire ko si gbodo danu, a wa mu egbo jenjoko ti a lo yi, a wa ro si inu re, a wa fi ewe jenjoko 10,a wa fi we, asi di ni owu dudu ati funfun, a wa fi sinu Isasun, a si fi epo si nigbati o ba jinna, lori odo ni obirin yi yio ti je, ese re ko si gbodo kan le, owo eyin ni yio Jẹ o, ewe tie tu yi, e fi ha palapala ogiri ni o.