OGUN GBANU GBAHA

Ogun gbanu gbaha, Eniti arun yi ba nse, inu re yio wu lati aiya de odo abe, o si le wipe oso ohun ni egbe, awon Ogun wonyi si kapa ré.

1. Epo jẹbo, epo-agboyin, epo ayẹ, egbo ọpe, egbo kakasenla, alubosa elewe lopolopo, a wa se ni agbo fun eniti ba nwu.

2. Egbo kakasenla, egbo oruwo, egbo ponhan, egbo legunsoko, egbo abafẹ, egbo egbesi, egbo apasa, adi, alubosa, ao se ni agbo, oluware yio ma mu, yio si ma fi we

3. Egbo arunjeran, egbo wawọn, egbo ojolagbọ, egbo ẹwọn agogo, egbo tude, egbo eruju, alubosa elewe, ao fi adi die si, eleyi jẹ agbo tutu, ao mamu, ao si ma fi we.

4. Egbo-agbasa, egbo osunsun, egbo aringo, ewe iyeye, egbo ewon agogo, egbo lapalapa lopolopo, alubosa elewe, ao se ni agbo, ao ma mu, a si ma fi we.

5. Egbo-isigun, agbasa, egbo sigo, egbo-arira, iru, alubosa, ata ati kahun, iyọ, a wa gun gbogbo re pọ, a ma fi mu eko gbigbona.

6. Igbo ẹkan, egbo-eruwa, egbo oparun, egbo-Ogirisako, egbo ako ibepe, ao se ni agbo, wiwe ati mimu.

7. Ẹrẹsile ewe ọdan, ẹrẹsile ewe ibẹpẹ, eresile ewe lapalapa, idaro ile run, odidi abọn eyin meta, ao ko sinu ikoko nla, a wa ko gbogbo ewe yi le lori, a wa fi eru awonka kan si, a wa da ni agbo tutu, ni ojo kesan, ni a to si, ao ma fi we, a si ma mu.

8. Ikun ojia, etu ibon, imi orun, ewe iyeye, ao lo iru, alubosa, ata, orogbo merin, atare merin, a wa gun gbogba rẹ po, a ma fi mu eko gbigbona.

9. Odidi siri ogẹdẹ were kan, ati isu idi ọgede, egbo ọgbinebo, ewe ọja ikoko, egbo oburo,ao se ni agbo ni, ao ma mu, a si ma fi we.

10. Ebo-ẹrun yan-ntefe, ewe arojoku, egbo kohinsorun, ewe-agbari eja, akasu eko kan, a fitele agbo na, eru awonka kan, ao se ni agbo, ao ma mu, a si ma fi we.

11. OSE Eresile ewe osan agbalumo, akugbe ewe koko ti afi nse ọbe, eru die, a wa sun ikarahun igbin, a wa lo gbogbo re po, awa po ose mo, ama fi ọṣẹ náà wẹ

12. Egbo ifon, egbo ipeta, egbo ipapo, ao gun mo ose, a ma fi ose na we nigbagbogbo

13. A sun kuku agbado, asun eso aidan, eru awola, ao gun gbogbo re po, a po mo ose, oluware oma fi we.

14. Eran oka, afomo ọdan, iso aparo, Ehule die, ao gun mon ọse, ao ma fi ose yi we nigbagbogbo.