Ose Awure

Ose Awure

OSE AWURE


1 Eiyele 4, Eku-ago 4, Eja-abori 4, Oga 4, Obi-
ifn 4, Óbi ipa 4, Yanrin Okun, Yanrin Osa, Imi orun, Ewe akisan, Ewe iyeye, ewe ljan, ewe ejinrin, ewe
Etiponọla, ewe Omini, Ewe-aje, ewe-Ogo,a o wa gun gbogbo re po, Ose sile mefa (6)


Ọfọ: Ẹlẹmo ni jan,ljan ni ján wonran, Ọgọrọgọrọ, Ogirigiri, Ogiri nda, lfa pele-adesan, Orunmila pele
Asande, Asan, lelẹlẹ Okun, Ako gbọwọle niti omidan,
Ako gbesẹle niti omidan, Ako yirun ejo, airidi Okun, airidi osa, Ifa ma je ki won ori idi mi, ara gbogbo ni
Sefunsefun fi saje, Ogo ni sọmọ elewiji, ẹnikan ni mo pe,
Igba ẹni lojẹ mi, Alakanle niti Òsumare, ewe pẹpẹ loni ki ire temi ko ma pe, ejinrin loni ki ire temi ko ma jinna
si mi, Ojumọ kimọ ki Okika ko ma ka tirẹ, ewe kan
labe lodo ire, Ire lónje,Ire gbogbo niti Omini, Ogun
dabede lọ re gbe ire aje temi wa loni.


A o fi iyerosun te Ogundabede a o da le ose yi lori, Ninu Igba-ẹru ni ose yi yio wa.Ao ma fi ose na wẹ.


Ako gbọdọ lo ọsẹ na ni Ojo Wednesday ati Saturday.

2. Ose 8/-, Igbin 2, Eiyele 2, Obi ajopa 10, Orogbo 10, Ẹyin adie 10, Iye aluko 10,Iye agbe 10, agbebọ adie Funfun, erupe oja 16, erupe agbede ọkọ,erupe gbogbo
ona ti o ba wo ila a bu diedie nibe, ewe Ogo,ewe
Omini, ewe Ojusaju, ewe Ire, ewe-aje,ewe akisan,a i
ha okurukuru alaso, erupe akitan,erupe Idiesu,Ake 2,
Aja 2, Ada 2, Igba-ewọn,a o toju aba,ao fikan ẹwon mọn inu opon, A wa gun gbogbo rẹ po, a wa ko sinu
Ọpon, gbogbo odu Ifa 16 afi lyerosun te, awa dale e lori, Ko ni Ofo o.


3. Igbín kan,alábahun kan,Akuk) ọlọdun kan 3, Ewe Ogo, ewe Ire, ewe-ijan, ewe-aje, ewe-gbegbe 200, obukọ Kan, erupe gbogbo ona ti o ba wọ ilu, Erupe ọja ilu
nla 7, Ẹwọn 200, Aofi iyẹrosun tefa odu 16, ao wa Tọju ikoko ajere nla to ba gba adie nla kan, ewe-ekuya, a o gun gbogbo re po mọ obuko, igbin, ati alabahun

a wa ko sinu iṣasun nla,a wa fi ajere nla bo. mọle.
A ofi akukọ adiẹ yi sinu ajere laye, ti yio ma gbe bẹ ,bi adiẹ yi ba ka ọdun 3, a mu-kuro, a si-fi omiran si, bia ba pari rẹ tan ni ori ajere, A fi ẹtu tẹ Ogundabede le lori ni ọdọdun


Ofo re: Olugbusi, jẹ ki gbogbo aiye gbọ esi temi si rere, a ki role ka gbagbe ote, ọnakọna lomi nba wọnu ajere, Fami nfa ọ, ni igba ẹwọn nfa ara wọn,
Agbele wusi niti akukọ, Ire gbogbo bayi ni ṣe oju owo


4. Ọṣẹ 3/-, A da si ọna 3, A fi ọkan ninu ọṣẹ yi ko erun, A fi ekeji ko ikan, A fi ẹkẹta ko era aladi, yanrin Okun, yanrin Ọsa, ewe adọsusu, Ìmi orun , Akukọ funfun ti ko ni ami, A tu gbogbo huhu rẹ,
agun mọ ọṣẹ yi, Ogundabede ni odu Ifa rẹ

Ọfọ re: Ẹsẹ girigiri ni mo odi ogan, ẹsẹ gìrìgìrì ní mọn aladi, ese girigiri lagiyan erun, airidi okun, airidi osa, airidi ati waye ọjọ, ewe adosusu won ki jo o lohùn nikan, bi adiẹ ba sunkun iyẹ, ihuhu a bo, a o maa fi ọṣẹ náà wẹ

5. OBẸ :Ewe olojongbodu, igbin kan, iyere ni ata rẹ

Ao re igbin si 10, nigbati o ba jinna, a wa fi iyerosun te odu ifa ogbe alara.


Ofore: Omi kunkun omi kun ọkẹ, ojojo lodo ntoro obẹlẹnbẹlẹ omi, ni tinu awo ara jade igbin mi fakuru refẹ, ifa o togẹ, ki o mu rere lemi fun mi wa, ọrunmila
o togẹ, ki o mu rere temi ti mbẹ nle aiye wa fun mi.

ọjọ ti a ba jẹ ọbẹ yi a ko gbọdọ Jẹ ẹran miran ni ọJọ pa. .


6. Ewe olojongbodu, obi ifin kan, obi ipa kan, iyẹ –
agbe kan, iyẹ aluko kan; ori aparo kan, ori ẹiyẹlé
kan, ewe lali, iyọ 7d, a wa tọju oru, a oko gbogbo rẹ sinu oru, a o tẹ ogundabede si, ìyọ ni a fi tẹ, a o tun tẹ ejiogbe si, iyọ ni afi tẹ.


Ofo rẹ:- A lu agba agbafọ, alu igi igiya, asẹsẹ fi kenkere kan aran oriṣa nile Olodumrae nro kendudu-kendudu, o difa fun Ọrunmila, baba nlọ ilẹ Ifẹ yio lọ re do si, nṣe ewe alajangbelumi o kẹrẹkẹrẹ nmọ gba lọwọ wọn kẹrẹkẹrẹ,- a wa ko gbogbo ogun wọn sinu oru, a wa so mọ oke ibiti a ba ngbe. Ki ba ṣe ibiti, a ti nta ‘ọja.


7. Ori aja, rọrọ ọdan, ẹfun, osun, ewe awẹde, a gun pọ mọ ọṣẹ 3.5d, a wa fi lẹ ori aja na, a má fi wẹ ọwọ.


8. IFOKOMU Ori agbe, ori-aluko, ori ,aṣa, ori awodi, ori akukọ, ori ọka, ori ere, odidi atare (11), orogbo (11), odidi ẹiyẹle kan, a o jo gbogbo rẹ pọ, a fi tẹ Odu-Ifa Ọsẹmeji, a wa rọ sinu atọ kan tio ba tobi, ẹkọ fi fọ mu ni oṣoṣu.


9. Eiyẹle meji, eku ago meji, adan meji, ọga meji, ọṣẹ ẹgbẹfa 3.5d, ewe ogo, ewe aje, a o gun gbogbo rẹ pọ, a o ko sinu igba-ẹru, a wa pa ewurẹ kekere kan si, a ro ẹjẹ rẹ le lori.


Ọfọ rẹ:- Ẹlọmonijan, ijannijanwọnran, ki okun ki okun, ki ọmọ adan ki orin kọrọyin kọrọyin, ifa mọ jẹki ire temi se mi, ori eku ki ṣepo, ori ẹja ki sebu, ogo de ọmọ ẹlewiji, ẹnikan ni mo pe igba ẹni lojẹ mi, ewe kan nbẹ lodo ire, ire ni jẹ ire, wiwẹ. ni.


10. Igbin kan, ewe kunkun, ewe ata, nigbati a ba ja ewe ilufẹmi ni a ma pe, afomọ ọdan, ewe ẹla, ilẹkẹ-
itun, ilẹkẹ- -ifa, abere, ọṣẹ, a gun pọ, a o ko
soju gingi, wiwẹ ọwọ ni.


11. Ori-itun, ori owiwi, ewe ọwọ, ewe kọnunkọhọ, afara-oyin igan, OWO ẹyỌ mẹfa, a o lọ ni, a wa gun
ọṣẹ pọ mọ; a ma fi wẹ.


12. Emina, alubọsa iṣigun, imi orun, a gun mọ ọṣẹ, a tẹ ọṣẹ na ni Ejiogbe, a wa pa ẹiyẹle kan si, a ro ẹjẹ rẹ le ọṣẹ na lori, a si fi ori ẹiyẹle na gun ọṣẹ ọhun lori, a wa da ẹtu si, ẹtu na aofi gbina lori ọṣẹ, Ao fi ìgi gbe i ìna .si ni o. Ofo re:- Ọlagbemika, ni ṣe aja. oriṣa, awọn ni WỌn ji, ni wọn sapa jubalajubala kalu, Ọrunmila ni bo a’ jẹ pe bi ti on ni, oni emina ni on o fi na wọn
‘lowọ na wọn lẹsẹ ti wọn o fi mu ire ti emi Wa, Alubọsa ni wọn Oo fi sale sana ti wọn o fi mu ire
ti emi wa fun mi, iṣigun ni wọn o fi ṣi owo ile wọn wa fun-mi, aran- kaiye ni orun ran, a ma fi wẹ.


13 Ewe ẹyin olobe, ajẹsi-ọrun adiẹ, ọti ṣẹkẹtẹ, a o
gun gbogbo rẹ pọ, ọwọ idi ni afi wẹ, a ko fi wẹ
ara, ni kọrọ yara ni a ti fi wẹ.


Ọfọ re:- Ọlamuregun ọmọ asawo ode Ẹgba, iwa mi
ku lẹhin awo ode Ijeṣa, lolo lawo ilojilolo, apo wọwọjojo ni ṣawo imokun, o difa fún orunmila baba nsawo lọ silu airiṣe, baba ni nṣe temi, bi nha sa
ṣe temi, lẹhin lẹhin ni olobe nso.


14 Ọṣẹ , Odu ifa rẹ ni Ogbe alara, ori aparo,
ewe ẹmilẹ, ilẹ okun, a gun pọ mọ ra wọn, a o ko sinu igba kekere kan.


Ọfọ rẹ:- Ologoṣẹ, abara finni, o difa fun agbigbo ni wọn ran ti nroju okun lọ re ko aje wale, bi ojumọ ba mọ aparo apera, bi ọsan pọn aparo apera, bi o ba di irọlẹ dẹdẹ aparo apera, ẹrun ki yan titi ki emilẹ ma
ṣe oje, ifa ma jẹ ki wọn o ridi mi. Otan