OGUN OWO

Owo dara pupo fun ijanba moto ati adare igi ati ija ogiri. o si dara fun owo Sango.

1. Ota ide merin, ota baba merin, ota oje merin, ati ota Irin dudu merin, ewe owo, ao se obi Ifin si (200) a sise obi Ipa si igba pelu (200) eyo atare Igba (200 a fi awo ako esuro pa apete kan, a wa ko gbogbo ogun yi sinu apete yi, a sidi apete na ni adipa, ao ma fi sinu ipo bi a nlo ibikan.

2. Ewe owo, ao sa ewe owo yi yio gbe dada, ewe ora, ewe Sanyin, ao sa gbogbo re yio gbe, labalaba merindinlogun (16), a wa fi sinu abo Owu a wa we ni onde sidi, awo pupa ni a fi ran onde na o.

3. Akuro alantakun merindinlogun (16) ayan (16) Eyo atare (16) ao tu iye kan ni apa otun akuko adie, be na ni ao tu ti apa osi na, ewe owo, ao be die nibi Igi panada. Ilu ti igi panada wa nisisiyi tio daju ni Ila Orangun a wa lo gbogbo re yio kunna dadaa wa fi te oyeku meji, ao pare, atun fi te odi mejejeji, ao pare, a wa fi te otura mejeji, ao pare, a wa si te ogbe kanran a wa fi sin gbere apako gbogbo ifa yi nio ni ofo o. .

4. Ewe owo ati egbo re na, aso laba sango, ao toro die nibe, atare aja meta, Igi nla die, ewe moloyin, ki omisinmisin gogoro 0, a wa jo, a fi sin ‘ gbere merindinlogun 16 ni atari ati gbere eyo kokan lorikerike ara.