OGUN SEJEBE

SEJEBI:Arun yi nigbati obinrin ba bimo tan eje yio po, ohun ti si nfa ni awon agbalagba, ati ki oyi o ma ko eniti o ba sese bimo tabi ki enia o sa ogbe eje le po, tabi ki omo o da oko tan, eje-yio po, ogun yi si kapa gbogbo ohun ti a daruko wonyi

1. Odidi alabahun kan, Ogede wewe ti ko ba ti gbo, ao sa siri kan nibe, ewe-abamoda, igbin kekere kan, ikakure lopolopo, ewe ogbo, ao jo gbogbo re po bi o ba se ogbe ni, abu si oju ogbe na, bi ba se sejebi ni, a bu die fun yio fi fo eko tutu mu, tabi ki o da si enu ki o fi omi sin si ohun.

2. Ako ofan ti o ba tobi, ewe anamo, ao su ni osuka, eso ido lopolopo, odidi atare kan ao jo gbogbo re po, aota si eje na bio ba se sejebi ni, o si le bu si ekisa ki o fi lapon bo, bi o ba si-se ogbe ni, ao bu ogun yi si oju ogbe na, Atufa gidi ni’ogun yi o

3. Igbin kan, opolopo ire, eso ila pupa, odidi atare meji, ao jo, ao ma fi fo eko tutu mu.

4. Ako ofan, ogiri, iru, ibepe dudu, odidi atare kan, ire lopolopo, agbado omola pupa, ao jo, ama fi fo eko tutu fun eni na, sugbon ise meji ni ogun yi seo. Mogun eleje ati atosi eleje, sejebi ni o si keta,

bi enia lu okan ninu awon arun wonyi, a le lo ogun yi fun eni na, were ni yio si fi sile.

5. Ire Lopolopo, opolopo isawiri, eje igala, agbado omola, opolopo ogongo, egbo igi amuje, ao ge kekeke, egbo sabale, a o ge kekeke, a jo gbogbo re po eleyi je ti sejebi, ao fi fo eko tutu fun obinrin na ni asiko na.

6. Igbin, egbo ogbolo, ewe isepe agbe, a o jo gbogbo re po, ama fise igbin je, a je obe yi tele ni nigbati obirin na ba ni oyun ninu, kise igbati o bade ori ikunle.

7. Ire, ewe awon ode, omunu ogan ipa, ao jo, a wa fi se eran ewure je, aje tele ni ey1i nao.

8. Odundun, rinrin, ẹwọ iroko, odidi alabahun kan, ire lọpọlọpọ, a o jo, a wa po po mọn ose, obinrin na yio ma fi ose na we, nigbati o ba ni oyun ninu.

9. Ewe sabale, ao lo ora ewure mo ewe sabale yi, obu otoyo, iyere, ewe agunmona, igbin kan, ora ewure si ni epo re, obinrin na yio ma je nigbati o ba ni oyun ninu, nitori ki eje ma ba po.

10. Panumo abafe, ewe patanmo, asun paripa, ẹsẹ ehin igala, a wa lo mo awon ewe yoku. nigbati a ba sun tan, a wa fise eran ewure je, aje tele nigbati obirin na ba ni oyun ni o.

11. Ewe ikupẹro, ikakure, ewe alupayida 16, ao lo yio kunna, a wa fi se opolopo esan je, iyere ni ata re obirin na yio ma je nigbati o ba ni oyun, nitori ki eje ma ba po ju ni ojo ti yio ba bi omo na.