OGUN OJU KOKORO

OGUN OJU KOKORO: Oju kokoro ko si ohun ti ko le fa, a ma fa ki omo a ma jale, ama mu ki omode o ma gbe owo iya re, a ma mu ki obinrin ma se isekuse, a si ma ti awon opolopo Io si ewon, o si nfa ki omo kekere ki o ma bu ile je, ko si ohun tio fa nkan wonyi bi ko se oju kokoro

1. Ao bu agbado sile lopolopo, a si tun bu ere na mo, a o wa mu die ninu eyiti awon adie ba je ku ninu agbado ati ere yi, a wa lo mo tiro, ati esuru pupa die, oluware yio ma le.

2. Itawere iru, jankawo die, akuro alantakun mesan (9), epa imi, a gun mo se, oluware yio ma fi bo oju ni ale ati ni aro

3. Monisere, epa imi, itawere iru, ao jo a fi sin gbere loju meji, eyo kokan la sin gbere yi o, oju kokoro na yio si kuro ni oju eni na.

4. Ao toju idin, iru, imi adie, itawere iru ose koko, a o pa po mon ara won, a wa lo ti yio kunna dada, a waa fi sin gbẹrẹ si oju eni na, gbere meta nia si fi sin, bi a ba lo ogun yi, bi omo na ba ri nkan oninkan, dipo ki omo na o mu ko ni le mu, ekun ni yio ma sun.

5. Itanna ido, eso werenjeje, epa imi, ao lọ dada, a fi sin gbere metameta si Oju.

6. Oju adiẹ mejeji, ewe emu, iru ẹyo mẹta (3), oju monisere aorẹ, ẹyo atare meta (3), ni a fi si, a wa lo yio kunna dada, a wa fi sin gbere métameta si isale oju mejeji