OGUN ORANORAN: Ogun oran ki je ki arun alarun o ran ni, gbogbo arun patapata ni ko le ran ni, bia ba se ogun yi si ara,

1. Esinsin 16 (merindinlogun), asẹ iru ekute, ase ejo kejo, a o lo, a o fi sin-gbere si orun owo mejeji, ati agbon ati ete oke, okokan ni ti agbon, ati ete o.

2. Labalaba merindiniogun (16), esinsin 16, ayan 16, odidi atare kan, ewe alupayida 16, awa jo afi sin gbere ni ipako.

3. Eiye ologesa, epa imi gbigbe lopolopo, odidi atare meta, ao jo, ao fi sin gbere yi idi ka.

4. Olubongaga, ekolo tio ba ku si oju ona, a fi atare aja kan si, ao lo, afi sin gbere yi idika.

5. Isawuru 40, ata pupa a o jo, apakan ose wiwe, apakan a fi sin gbere yi idi ka.