OGUN ORU INU

OGUN ORU INU Oru inu je arun tio buru ju ni ara obinrin, asima ba nkan je pelu lara obinrin, awa enia dudu aki pe Oru-inu ni nkankan sugbon ohun pataki ni:

1. Igbin kan, ile aladi, a o jo mejeji po, ati odidi atare kan, ao ma fifo eko tutu mu.

2. Ile aladi, siri ogede wewe kan, imi adie ti o wa ninu ago lopolopo, ao jo, ao ma fi fo eko tutu mu.

3. Ile aladi, ikun ogano, odidi erin agbado meta, oju oro, a o jo gbogbo re po, ao ma fifo eko tutu mu.

4. Rintin, odundun, ogede were, igbin, ao gun igbin yi tikarahun tikarahun, eresile ewe ipin, iyere, kanhun bilala, a gun ghogbo re po, a wa sasi ehin igba, a ma fi mu eko gbigbona.

5. Omi yinyin, obinrin na yio ma mu nigbagbogbo.

6. Ewe elu kowe, ao gbo ti yio toro dada obinrin na yioma mu.

7. Omunu olonra igbo, ao gbo ti yio toro dada obinrin na yio-ma mu

8. Ewe obi gidi, ao ja ti yio po, a wa gbo a fi ase tabi ajo gbe omi re, obinrin na yio ma mu.