OGUN OGODO

Ogodo je ohun ti o le ba enia je, ni akoko beré re, yio ma ro eni na lara, bi lakuregbe, nigbati o ba wa da éni na gunle tan, gbogbo ara re yio wa si tolotolo bi igbati sanpona ba fi owo ba enia, Ipa ogun yi si ka ogodo gidigidi, ohun tia si le lo fun ogodo ni awon nkan ti a ma fi sibé yio.

1. Epo emigbegiri, egbo inabiri lopolopo, egbo enu opiri, oro agogo ao wa egbo re egbo oro adete, epo ira tutu lopolopo, efun, osun die, a wa ko sinu agbo a si ta moriwo mo ikoko agbo na, nibiti a ba ka agbo na si, obinrin ti o ba nse alejo ko gbodo de ibe, okuta ako nla nla ni a gbe ka ile nibiti a gbe se agbo na, obinrin na yio ma mu yio si ma fi we.

2. Epo osan, egbo sigo, enu opiri, dangborokun, agbonrin egbo re ni, elomiran si npe ni dangborokun agutan, a wa ko gbogbo re sinu ikoko, a se wiwe ati mimu ni agbo yi wa fun osi dara pupo fun ogodo.

3. Egbo inabiri, egbo enu opiri, egbo-oroadete, ewe asin, eru awola, a wa gun gbogbo re, ologodo na yio. ma fi we, pelu ose ni a gun o

4. Epo-jebo, epo-igi ayan, epo igi agbonyin, baka, enu opiri, egbo inabiri, obuotoyo, alubosa onisu, epo kotopolin awongambari, won ntao, iyere,a wa gun gbogbo re po, oluware yio fima mu eko gbigbona.

5. Ao mu somiroro ti o ba tobi, ao sun ni ina ao lo sinu adi eyan, oluware yio ma fi pa gbogbo ara.

6. Somiroro, etu ibon die, ao lo po, ao wa da sinu adi, eni na yio ma fi pa gbogbo ara, yio si ri wipe gbogbo batabata ara re ni yio kuro.

7. Egbo awuje papanla, isu ogede odo, epo ira, epo igi Ori, enu Opirl, epo emi, egbo sajere, egbo ekunkan, emu ni a fise agbo na, ogidi emu ni o. Oluware yio ma mu yio si ma fi we.

8. Ewon agogo, epo pandoro, egbo ido, egbo-gbodogi, ewe Sabale lopolopo, aran ope ti ko ba ti yo ninu abobo iya re, ni a fi tele agbo na, eru awola lopolopo, ogangan aro ni a fise agbo na wiwe ati mimu nigbagbogbo.