OGUN OSI INU

OGUN:

Omode ni arun yi iba ja, ari olo ota ni egbe re, osi yi si yato fun olo ikun ti a pe ni olonu, Osi inu ki si tete han bi olo inu, Osi inu yio dabi igbati obirin ba ni oyun le omo, omo na yio si bere si gbe, laije wipe iya rẹ ni oyun le, irun ori omo na yio si wowe, tabi ki irun naa daru, ohun tia si le lo ni wonyi o,

1. Itakun alukerese, egbo-feru, egbo-agba, ati eso re, eru awonka, a wa se ni agbo, ni ori ina omo na yio ma mu, yio si ma fi we pélu.

2. Epo-pandoro, egbo-seyo, eso agba, alubosa elewe, a wa se gbogbo re po, ti yio jinna dada, omo na yio ma mu, yio si ma fi we nigbakugba.

3. Egbo feru, egbo efinrin aja, egbo-agba ati eso re, eru ewonka eyo kan, a wa se ni agbo ti gbogbo re yio ro dada, omo na yio ma mu, yio si ma fi we.

4. Ewe ejinrin wewe, ewe alukerese, eso agba, eru awonka, ao se ni agbo omo na yio ma mu yio si ma fi we.

5. Eso agba, ao yo Ẹgusi inu re, eru awola a o lo mo ewe efinrin aja, a gun ni ọṣẹ, ama fi wẹ ọmọ na.

6. Eso agba, ẹru awola, egbo feru, omunu ewe kakansela, a gun gbogbo ré po mo se, ao ma fi we omo na nigbagbcgbo,

7. Egbo akiti tutu ati eso re, ao pa eso re pepe, ao wa yo ẹgusi inu re, egbo ipẹta, gbogbonse, ẹru iju, ati egbo feru, a wa gun gbogbo re po sinu oru nla kan, adi, ori, alubosa elewe, ipara ni eleyi je o, yi o ma fi mu eko gbigbona, bio ba we yi osi ma fi para.

8. Ewe efinrin aja, jankawo die, oko atare kan, ao lo po, a wa fi sin gbere si egbe na, gbere na ko ni yeo

9. Epo osan agbalumo, ati egbo orombo wewe, eru awonka ati eso agba kan, a wase ni agbo, oluware yio ma fi we, yio si ma mu nigbagbogbo.

10. Egbo feru, egbo kakasenla, egbo yanrin, egbo koleorogba, ati eso agba kan, eru awọnka kan, omikan nia fi se agbo yi, oluware yio ma fi we yio si ma mu nigbagbogbo.