OGUN LATANLATAN

OGUN LATANLATAN

Lataniatan je arun ti o buruju ninu gbogbo arun fun Obirin ki je ki obirin oni oyun, nigbakankan. Bi aba si se ogun yi ni agbara Olorun, were ni yio ni oyun

1. Egbo igi aka, ao ha epo re sinu igba kan, ao sun egun ese etu, ewe etu, ao lo yio kunna, iyere, eran etu ni a fi gbogbo nkan wonyi se fun obirin na.

2. Itan etu, ewe agbari etu ati egbo re, omunu ewe aka, mudunmudun egun malu, egbo-sajere die, iru, alubosa, ata were, iyo, ao se ni obe ti yio jinna dada, obirin na yio ma je.

3. Ẹran ẹtu, ewe-agbari etu, igbin, ewe-apakọ, ao lọ, a wa fi se eran etu ati igbin yi je.

4. Egbo eruwa, okuta ako, iko odide, ao lo gbogbo re po, awa pepo mo ose, obirin na yio ma fi pa itan, yio si ma fi we pelu.

5. Egbo igi aka, ao ge kekeke, odidi aparo, egun itan etu, a wa ge gbogbo re sinu agbada, a wa jo gbogbo re po, a o mu die a po mo ori, a o po die mo ose, a ma fi iyoku fo eko tutu mu, eyiti a po mo ori yi, yio ma fi ra itan, eyiti a po mo ose yio ma fi we.

6. Ọmunu ewe osunsun, Egbo apata ati ewe apata, ao lo yio kunna a wa fi se eku eda je, obinrin ti latanlatan mu yi ni o ma je.

7. Egbo owu ikoko, o n na si ni won pe ni ado susu, egbo-akoko, egbo-arunkojori, ao se, obirin na yio ma mu, lasiko ti oba nse alejo.

8. Egbo-ope kannakanna, egbo logbokiyan, egbo aka, ao wa se ni agbo obirin na yio ma mu, yio si ma fi we ° nigba gbogbo.

9. Egbo-ogunbere, egbo sepolohun, epbo-anikansegbo, alubosa elewe, ata were, kanhun bilala, iyo, a wa lo gbogbo re po, a ma fi mu eko gbigbona.

10. Isu gbegbe, etu ibon, odidi itan etu, alubosa elewe, monigedegede, iru, kahun, iyo, a wa lo gbogbo re po, obirin na yio ma fi mu eko gbigbona.

11. Egbo-efo ati eso re, egbo-agbasa ati ewe rẹ, eran etu gbigbe, kanhun bilala, alubosa elewe, iru, iyo, awa gun gbogbo re po, obirin na yio ma fi mu eko gbigbona.