OGUN JEWOJEWO

OGUN JEWOJEWO

Ogun yi dara fun omode, ti jewojewo ba nje omode ki je ki osun, ki isi je ki omo o sanra, arun yi ama la isan wara wara ni ikun omode, a si ma la omode lori pere, elomiran a ma pe oka ni, ti aba nlo egbo igi yi fun iru awon omo na, yio sanra, yio ni alafia

1. Ewe dagunro-Igbalode, ewe abe alarun, ewe ologun sese, ewe awusako, eru awonka kan, ao se yio jinna dada, omo na yio ma mu agbo na.

2. Ewe ojusaju, bi o ba se okunrin ni omo na, ao di si ona 9, ao di eru kokan mo, owu dudu, ati owu funfun ni a fi di mo, ewe iranje, ao se ni agbo, ao ma mu a si ma fi we omo na, ogun yi dara pupo.

3. Eno pandoro, epo afa, alubosa elewe, eru awonka kan, tangiri kan, bi o ba se okunrin 9 ni a o la, bi o ba si se Obirin 7 ni ao la si, ao se, omo na yio ma mu.

4. Ewe agbari etu, akasu eko nla kan, eru awonka kan, akasu eko yini ao fi tele o, ao wa se yio jinna dada.

5. Itakun ejinrin were, egbo orombo were, epo ogano, epo kuere, eru awonka, a o se omo na yio ma mu, yio si ma fi we.

6. OSE: Ao gun ewe oja ikoko, ewe ilasa, etu ibon, imi orun, somiroro, ao gun gbogbo re po, a o ma fi wẹ, ogun yi dara pupo ti iwo ba lo, o mo pe ogun gidi ni.