OGUN LOBUTU1 Egbo ako ibepe, ewe re ati epo re, egbo ahun, ewe re ati epo re, egbo afoforo, ewe re ati epo re, eru awonka a o se, oluware yio mu, yio si ma fi jo ara.

2. Etu ibon, egbo ako ibepe, egbo orombo lakuregbe, isu gbegbe, alubosa-onisu, lyere, ata pupa, Orogbo 9, atare 9, iyo, ao gun gbogbo re po, oluware yio ma fimu eko gbigbona lararo.

3. Isu-gbegbe, egbo tude, egbo ifon, egbo inabiri, itan-etu gbigbe, kanhun bilala, alubosa elewe, iyo, ata, ‘ao gun gbogbo re po, ao ma fi mu eko gbigbona larọ.

4. Epo oganho, ao lọ yio kunna pelu kanhun bilala, ao ma fi mu oti ebo.

5. Epo ogano, ao gun pelu ewe asa (taba) ao ma fi oti ebo si, a o ma fi pa oju lobutu na.