OGUN EDA

OGUN EDA

1. Ewe lari, igbin kan, agbado omo nla pupa, alubosa, kanhun bilala, orogbo mesan, atare mesan, iyere, ao lo gbogbo re po eko gbigbona ni ao ma fi mu. o dara pupo.

2. Orogbo gbigbe, atare mesan, era, esan ekuro, a lo gbogbo re po. eko gbigbona ni ao fima mu.

Ofo re: Ijoko ni ise idi, didun ni ise eiye, salekitan ni bure adie, o difa fun arun gedegbe ti se omo ọlọyọrọ. Ni nse lagbaja o.

3. Agbarin dudu, ao lo po mo patanmo, eru awonka a o lo po mo ose, titaba ni.

4. Etu ibon, egbo iragbo, igbin kan, kanhun bilala, iyere, ao gun po, ao su rodorodo, ao ma fi mu eko gbigbona laro laro, ao lo ewe lari die mo.

5. Ori ahun, ibo oju igbin, iwonran olokun, a o jo po, nigbati a ba jo tan, a o lo etu ibon si, ao ma fi fo eko tutumu.

6. Ahan aja a o re, eru awola, ewe loko lepon, ao gun po mo ose, obirin na yi o ma fi ta ba.

7. Eso-labelabe, agolo siga meta, adie ti o ba ye ri, orogbo meje, atare 7, nkan obe (iyọ), alubosa elewe, ata were, ao gun gbogbo re po. A o ma fifo eko gbigbona ati okunrin ati obirin ao mu.

8. Igo opalamba funfun onigun merin, orombo 9, atare 9, iyere, ifofo olokun, kanhun bilala, lehu ope, okuta ako, egbo aka, ao gun gbogbo rẹ po, ao lo gbogbo re kunna. Ao ma fi mu eko gbigbona.

9. Agbarin eyo kan, odidi atare kan, ewe patanmo, ao kan oje lapalapa sinu fitila, ao gun po mo ose dudu, obirin pa yio ma fi taba.

10. Igbin meji, orogbo 7, atare 7, ewe ipin ti o re sile, kanhun bilala, iyo a o gun po, a o ma fi mu eko gbigbona lararo.

11. Igbin kan, ewe ori, ibo oju igbin, odidi atare 3, a o jo po, lehin na a o lo etu ibọn mo, ao ma fi fo eko tutu mu.

12 Egbo akiti, nigbati a ba wa egbo igi yi tan, ao bo obi pupa awe meji ati funfun awe meji si ibiti agbe tan wa, egbogi yi, Iehu ope, ti aba ha lehu ope yi ko gbodo kan ile, titi ti ao fi dasi ibiti ao gbe gun. odidi atare kan, a wa gun pọ ao ma fifo eko tutumu

13. Ewe patanmo, ewe emo, ao gun po mo ose, wiwe 3 be fun obirin na.

14. Ewe lapalapa ti o re, orogbo mesan, atare mesan, lyere, iyo, opolopo alubosa elewe, iru, kanhun bilala, ao gun po, ao ma fi mu eko ebigbona

15. Egbo orokoro lọpọlọpọ, ogidi emu, egbo tude, ao se yio jinna, obirin na yio ma mu, sugbon ni asiko ti obirin yi ba nmu ko gbodo ba okunrin lopo

16. Igba owo eyo, ao lo owo eyo yi ni, igo opalaba, ao lo obi ipa merin, obi ifin merin, kanhun bilala, ifofo okun, ao lo po, ati iyo yio ma fi mu eko gbigbona.

17. Imi eiyele lopolopo, patako ese esin, irun ori tia fi ha palaka ogiri, ao mu nibe, ao wa jo gbogbo re po, obirin yio ma fifo eko, okunrin yio ma fifo eko tutu mu.

18. Ewe abo a di ni iti mesan, iyo 6d, kanhun 6d, egbo ipeta, iru 6d, ao wa se ni agbo obirin yio ma mu titi di ogbon ojo, ko gbodo ri okunrin.

19. Adie tio ba ni eyin ni inu, ao pa adie yi, ao wa ko gbogbo ifun adie yi, ati eyin inu re sinu odo, eso labelabe, erin agbado meta, odidi atare 6, orogbo 6, kanhun bilala, iyere 20 wa gun gbogbo re po. Eko gbigbona ni ao ma fi mu.

20. Igo opalanba, lehu ope, obi ajopa mewa, orogbo mewa, ogede agbagba meta, egbo aka, eja abori nla, kanhun bilala, iyo, lyere, ao gun ao fi mu eko gbigbona.

21. Egbo atori, egbo asunhan, ogede wẹrẹ dudu, ao bo ao mu ogede inu rẹ, tagiri ao be epo re kuro, ao wa gun iyo ati kanhun, atare 9, orogbo 9, ao gun ni agunmu, mimu eko gbigbona ni.

22 Igbin kan, egbo alugbo kuta, orogbo 4, atare 4, kanhun bilala, apopo obi alawe merin, ao gun po, ao fi ma mu eko ti a ba lọ tan.

23. Lehu ọpẹ, ewe ẹmọ,emọ agbo lọpọlọpọ, emo abero de ife, emo ajaho, epa isu ti o jona mo ikoko, ihaho ekọ, epo ẹmọ a o jo gbogbo rẹ po, eko tutu la o fi ma fọ mu.

24. Esan ekuro, obi-gidi ati orogbo lọpọlọpọ, ao lo esan ekuro yi yio po, kanhun bilala, nigbati a ba lo tan obirin yio ma fi mu eko gbigbona.

25. Odidi erin agbado 3, erele ipin, igbin, aso waji, kanhun bilala, ao gun ghogbo re kunna, eko gbigbona ni ao fi ma mu, ọkọ pelu aya

26. Eso bara, okuta ako meje, epo iyeye, eru awọnka, ao fi ogidi emu se ni agbo yio ma mu. Obirin ati okunrin ni yio ma mu, bi atosi mu eni na pelu.

27. Agbo mimu ni, egbo peregun, egbo ipapo, egbo sapo, egbo orombo were, egbo orombo lakuegbe, eru awonka, kanhun bilala, ao se mimu ni orọ, losan, lale.

28. Egbo Isẹpẹ agbe, egbo senifiran, epa ikun, kanhun bilala, ao se lagbo, nigbati obirin ba nse alejo ni yio ma mu, lemeta lojumo.

29. Igi ero aya, awa egbo re, alo yio kunna, alo alubosa ati baka mo ogede agbagba dudu, epo sinle, a fidin pekere, ao ni wa kuro ninu epo yi, inu re ni won o ti ma je ati oko ati obirin.