OGUN GBOFUNGBOFUN

OGUN GBOFUNGBOFUN

Gbofungbofun je arun ti ole tete pa enia, nitori ki je ki enia o le jeun, ama mu ahon dudu, omiran asi ma mu ahon funfun, tia ba si lo ogun yi o ka pa re were ni yio fi oluware sile.

1. Epo ira, a gun ao fun omi inu re, omi orombo were, alomu, oti-ebo, ao ro sinu igo oluware o ma mu.

2. Ewe owe-ahun, epo igi-ori, a o gbo ewe owe ahun yi omi re yio po, a o gun epo igi-ori yi, omi orombo were, oti ebo, ao ro sinu igo, mimu ni.

3. Epo-ira, epo-igha, kahun bilala, alomu, somiroro die, omi orombo were, ao se yio jinna dada, a wa ro gbogbo re sinu igo ni ojo na, ao wa so ro si oju ina mimu ni, ife kekere ni ao ma fi bu mu.

4. Epo ira, epo agbonhin, egbo awusa, ewe taba die, kanhun bilala, ao se yio jinna dada, a o ro sinu igo, mimu ni.

5. Egbo-tude, egbo-ira, isu-ogede-odo, alomu die, somiroro die, ogidi emu ni a fi se, bi a ba se tan, ao lo ata die si, a o ro sinu igo, ao so mo oju ina. Mímú ni

6. Egbo-sigo, egbo-ira, egbo-apasa, kanhun bilala omi-kan, alomu die, somiroro die, oti oyinbo, ti a ba se ti o ba jina tan, ao ro sinu igo, ao so si oju ina, mimu ni.

7. Ewe fulawa, ao fi sinu ewe ogede, iyo die, a bu sinu ina, ao fun omi re sinu awo kan, mimu ni, o si dara fun omode pupo.

8. Oje ogede, ao ma to la, bi o ti mo yi ẹ ma fi oju di, a ma je pupo, bi ina ni je.