OGUN GBEYINRIN (tonic clonic seizure)

OGUN GBEYINRIN

Arun yia ma mu ehin le toto, a ma mu ehin wa po. Eyi ki ise giri o, osi le ju giri lo.

Opolopo enia di ope arun yi ni Magun, Beni ki isi se magun, ti arun yi ba ti da enia lehin ama pa enia o.

1. Opolopo ogongo-akitan, omi oja ijoko, omi iru, egbo egburu, egbo-bonni, egbo eru tapa elomiran npe eru tapa yi ni arere, omi-oja ikoko, omi iru, egbo egburu, egbo bonni, ati eru tapa, ao se awon wonyi ni, nigbati a ba se tan ti a ba ro sinu igo ni a o wa po ifun ogongo yi si, ao wa so mo oju ina, Mimu ni.

2. Ọpọlọpọ okunrun mọka, ao lo okunrun moka yi, ekolo lopolopo, ati ifun ti edo nti o ba wa ninu pepeye, igbin kan, ao yo kuro ninu ikarahun, ao wa gun gbogbo re po ni tutu, adi, ori, epo, obuotoyo, ao wa fi sinu isasun ti a ti nlo ti ko si le jo, a ma fi rara, a si ma la. Bi enia ba fi npara ti si nla, wọ ni gbogbo re yio ro, ti yi o si san tan patapata.

3. Egbo bomubomu, ewe aragba, epo afon, epo afa, egbo arunjeran, egbo ogan pupa, egbo oruwon, omi okusu-aro ni a fi se agbo na, yio ma fi we yio si ma mu.

4. Egbo wawon, isu gbegbe, ati ewe gbegbe, egbo bomubomu, ogede-odo, ati alubosa kan, igbin 7, isu ogede were, epo pandoro, a o se ni agbo a o mamu, asima fi we.

5. Igi taba, tangiri, rinrin, okunrun tio ba ku si oju ona, ao jo, a o po mo adi, ao ma la.

6. Odidi ejo kejo, tiaba pa lojo, ao si jo ni ojo na, odidi alabahun kan, ao jo, ekolo ologi ao jo, ose ni a ma po fofo re ni, ama fi rara, asi ma fi we. Osena o dara pupo, papa o dara fun giri, ti iwo ba lo iwo yi ori ise re,

7. Igbin kan, egbo tude die, egbo inabiri die, ori, epo, iyere, egusi-itoro, ewe amunu tutu, ao se ni obe, alamodi na yio ma je

8. Egbo odofin igbo, egbo ọgbọ, egbo eru tapa, eru awola, ose ni, ao ma fi we alamodi na, o dara pupo.

9. Ewe koleorogba, ewe agidi mogbonhin, ewe worowo, ewe kasan, ewe ailu, egun ehin oka, igba ehin alabahun, ehin adie, awon ehin wonyi ni afi tele ikoko ao se ni agbo, a ma fi we a si ma mu.

10. Boribori gbogbo re ni yi o: Egbo bomubomu ati ewe re, egbo kasan lopolopo, epo afa, egbo sapo, ewe agunmona, egbo logunsese, ito akọ esin, ito malu, omi okusu aro, ao se gbogbo re po a ma mu a si ma fi we.