OGUN ERO

OGUN EKO

Ogun ki ero le bo, bi obinrin, ba bimo tan ti o ku okan yoku, tiko bo, eleyi ni anpe ni ero, tia ba si lo ogun yi, were ni yio bo.

1. Ewe-gbegbe, aso waji, ati etu ibon, ao lo etu ibon yi ni, a wa fi te ifa ejiogbe le ori aso waji yi

Ofo: Ayoru, afawo, akiwo, fi gbegbe gbe wa, fi waji ji wa, fi etu tu wa, awa fi aso ti a te ifa le yi mu okun ibi omo, a Wa ma taika si, were ni ibi na yio si bo.

2. Ewe koko, ao te ejiogbe efun lowo kan, osun lowo kan.

Ofore: Mudunmudun serere (3 times) mudunmudun sarara 3 times, onala re fe, eran wonu egun, egun wonu eran, omo legun, obo tu enu egun re sile, awa fi ewe koko yi di ekeji omo na mu, a wa ma taka si titi ti yio fi bo sile.

3. Ao mu eyin adie kan, a la ni efun, eyo atare merinla a je ienu, tio ba je wipe ko ti bimo ni, ni dodo nia gbe pe ofo yi si, bio ba bi mo tio ba je wipe ekeji omo nio ku, lehin nia si gbe pe. A wa fi eyin adie yi kan ni ehin, tabi ni idodo, awa fo eyin adie na mole lojiji, a wa wipé:Alapa aja 3, eledede 3, onida kosokoso 3, ajanaku gban mi je ko de le wi 3, para ni akeke la gi 3, omi gbigbona ki gbeni pe o. Ewo orisa ni, eyin adie ki kuna.

4. Ofo re: Eyo atare meje, la ma je lenu, Asalaga ofese mejeji sokun agba waiwai, opa tere idi ase ona, orisala, ataro kutukutu ni onile ti gbe eko de o yara wa je loni dandan ki esinsin ko ma ba fowo kan ọ o

5. Atare meje la fi pe: Onile mola pepe alajumo ekule o mu ni de fe ni oluwo eni omu mi de fe ni baba, eni omu ni de fe lo de yi oni kio kalo o, o ni dide nile lai o ka lo, ki olufe ma ba ba owi, alejo bode onile ti kuro nile, a watu atare meje si ni ehin. Fila ti a de sori a fi na obirin na ni emeta Iehin.

6. Pelu eyo atare meje, tia ba nje lenu nia fi pe o

Yangi abori kugu, o gbe inu eje so sin, ogbe inu eye sora. sebi eru elegbedi lo se, elegbede lo si nbo wa yi, ma je ki oba o nile o, ki o ma ba ba o wio.

A tu atare meje si ni ehin, were ni yio si bo sile.

7. Ao mu iyo ao fi te ifa ejiogbe, a wa wipe ose rere, osa rarara. Apo Olorun, osere loruko ti a npe omira, osara ni oruko ti a pe iwo ogerere, apo Olorun ni oruko tia pe iwo obi omo, puru lewu tu, fo lo mi baluwe se, ao tu si ni ehin.

8. Ao mu atare meje, ao je senu Ao si je eru meje, ao si wa mu iyere osun, ao fi te ifa osa meji, ao wa pe Ofo na si enu ona ile

Ao wipe oyigi lawo yagba (3ce) Eji kukuku Ie hin abo igede (3ce) biri biri pi ifa le tiri timo fi ran yin ni se, te nfi lo tititi, won ni se bi iwo osa meji ni o ja diju, ifa ni e wipe tipetipe ni akika bi, tipetipe ni orire bi, bi afon ba ja loke panti kan ki da duro, A tu si enu ona, were ni yio bi.

9. Ao bu omi yio kun inu igba ademu, a wa fi iyere osun te ifa ejiogbe, a wa wipe ki gbogbo awon ti o ba wa nibe pe ki won ko kuro, a wa sure lo si ibiti ina ba wa, a si mu ogunna kan sinu omi yi.

A wa pe Ofo yi: Olusomiro omo ogun, ewon ja giri omo oduwa ate ewon ro, olugba pamo loruko tia pe iwo obo omo yemo, iya mi osoronga o di owo yin o, obo munimuni obo munije, obo gbomo mi teriteri obo loran nbere oran re, obo gbomo ni loruko ti a pe iwo ọlẹ, oloran ti bere ti eni Olorun, ma jeki oloran ti bere tire ka ọ mo ibe o. Fi omo olomo le o. Ihoho la duro tia ma gba enu ona labara ti a fi gba ni abara merinla.

10. Ao bu omi, yio kun nu igba ademu. A wa wa ibi ina bawa, a o fi owo mu ogunna kan si inu igba ademu na

Ofo re:Ao fi iyerosun te ifa ejiogbe. A wa wipe ki gbogbo enia tio wa nibe ki won kuro:A wa wipe A! pa, A! pa (3ce) iya mi osoronga, mo ro aiye moro mo, (3ce) aiye moro lorun, moro mo, Ai moro nisale yewu ni mu ni dun idun ekute fin fin, lodifa fun akoni kuro tise omo obo lorun, baba wa iwo lobi iya wa iwo lobi, Olorun ki dajo mabi, otito ni ti Olodumare ti da, wo na rerere lorun, awa Wipe A! ina mbe, mbo, mbo Iwo aje to wa nibe i ina rere de, a ta epo sile be ti o ba bi omo na tan.

11. Eyo atare mesan, eyo agbado mesan, eyo oka baba mesan, ao je lenu, yio si kunna, a wa pe Ofo re: Pe ola da da, adakolonko adakolonko, re wi ma re wi mo o, adakolonko la pe oso, ori wi loruko ta pe iwo aje, omo olotun ase ẹwẹ ta lo ti de ori ikunle titi, bi ohun ba ti e sonu, ase oju olohun, oro yi wa se Oju Olodumare bi? ko se oju Olodumare, abi kini awa je nile, fun wa ni mu tan, fori soju, fun oluta abenu pinmi, animutan fori soju lape oso, oluta abenu pinmi la pe aje, oporo ti bo low ile bo idin, la pe Olodumare, iko nla ki bo lowo baba mi arara mo sa, ina nla omo arara ri jojo nbe lowo Olodumare ti fi jo ni kiri, iya mo gba na yi duro, iya ti o ba gba ina yi duro airi Omo eni iyi kiana o, mo omo elewa ata ewa ta ori sile o, a wa sufe lemeta. Lesekanna ni yio bi omo na.

12. Eyo atare merindinlogun ni ao fi pe ofo yi si ori idodo obirin na

Ofo: Aiye mole la pee aiye, mole lape idin, aiye mole la fi osa se awa, mo fi sawa, ma fi sewo, ma fi sewo; ma fise orike, olobo ayeke, olobo ayeku, ina ki jo nile ki o nile ko riran, kio duro de ina, ejo kidi gbo pade enia lona, egbe agbonrin ki ri ibon lehin okunrin ki o duro, bi a pa ire a ki ba eje nibe, eje maya osun, eje ma ide, moya ona momi lode orun, were ni ewure bi, ti pe bi ba esin, lori ibi, orere de omo da, moda omo duro lode orun o, ki olode orunma ba ba ni wi, ao tusini atari.

13. Ibi ewure, ibi-agutan, ibori-ila, ibori ikan, ere sile ogede were, a wa jo pelu odidi atare kan, aboyun na yio ma fi fo eko mu nigbati o ba ni oyun.

14. Eso ibepe ti o ba bo sile funra re, pandoro tio ba bo sile funra re, ibori ila, ibori ikan, a fi odidi atare kan si a wa jo gbogbo repo, aboyun na yio ma fi fo eko tutu mu, nigbati o ba ni oyun ninu, ki yio si si idaduro ni ojo ikunle, bio ba lo ogun yi.

15 Opa isu, ao fa opa na yo, odidi atare kan, owo ibiti owole nidi opa isu na, a wa jo po mo atare, ogun yi ko ni je ki ibi omo o tobi, nigbati a ba jo tan, obirin tio loyun yi yio ma fi sinu epo yio si ma la.

16 Oko-ogede were, atare kan, ao jo po dada a wa da sinu epo, ao ma la.