OGUN ISOYE

Ogun Isoye dara pupo. Awon omo ile iwe ati awon emo ile-keu ni Ogun Isoye dara fun julo. Ohun tia si le lo ni wonyi

1. Imi aparo, Imi esin, Iwe-adiẹ, akukọ, awon ewure, ewe-oniyeye, etutu eran esin, a o jo mo odidi atare kan a wa te ni obara nikosi.

Ofo re:Alara loni ogbon, alagotun lo ni imoran, emi ori kerengbe iyegungun borun ganganran, ki nmu pon omi fun baba wa, ala osere, ko fi mu omi, o difa fun orunmila, won ni ogbon koye koyede, Orunmila ni bi o ba je wipe bi ti on ni, ba je wipe bi ti ohun ni, o ni o to gegege ni imi aparo, gege ni imi esin ko ara won, eyi nba ja ngbagbe, iran ko ran mi leti re, bi adie, ba jeun, inu iwe re ni je si, Awon ewure Inu ewure ni gbe si, Ona merindinlogun ni mbe ninu oniyeye, gbogbo re ni fi mu omi, eyl mba ja ngbagbe iran ko ran mi leti re. Ma ko mi ni iye mi lo, obara nikosi.

2. Ewe-oniyeye, kuluso 16, etutu eran esin ti o ba ya aketun merindinlogun, ao lo, awa fi su olele, ewe iran ni a fi pon ole na.

3. Ewe oniyeye, a o tu iye abiya akuko ni ona mejeji, abeyo ogede, abeyo esun, ao lo gbogbo re po awa fi din akara je.

4. Ewe oniyeye, ewe iyeye, kuluso 16, etutu eran esin, ewe-sejetoro, ila, ao lo gbogbo re po, a wa fi se obe ila je.

5. Ao fi iyerosu te ifa ejiogbe.

Ofore: ewon ja, ewon so, atan wo, ifa ni, iwe ni, kewu ni, ko wo sinu mi, awa da sinu epo, a ma to la.

6. Ewe-oniyeye, ewe sinkinmini, -ewe ominsinmisin, imi esin, a wa jo gbogbo re po, a wa ma fi ro ekuru je.



7. Ketenfe ti nbe nidi eran, etutu eran esin, abeyo ogede, a wa fi koko ori kan le abeyo opede yi lori, nigbati ori yi ba yo tan, a wa ge eyo ogede na, abiweku adie, a wa jo gbogbo re po, a o ma fifo eko tutu mu.

8. Tada ti awon Imole fi hantu, a wa toro opon wala ti awon Imale ma hantu si na, igbako eko, igbako oka, Ori awoko, Ori agbe, awa jo gbogbo re po ma opon wala yi, a wa ma bu sinu tada, la wa ma la.

9. Ewe-oniyeye, kuluso 16, Ori awoko, ewe Isepe agbe 16, Ewe isoji, ewe tia npe ewe isoji yi ni a npe ni ewe ojiji, a o wa wa alake oju ona 7, awa jo gbogbo re po, awa ma po mo ere tia ba lo, awa ma fi din akara je.

10. Eran esin, enu ona ogan ti o ba ni ikan ninu, gbogbo enu ona naa ni a bù karikari diẹ, ewe isepe agbe ati ewe iyeye, ori eiye ibaka, odidi atare aja meta, a wa jo, ama fi la oyin

11. Eyi je isoye gidigidi ti omoede ba nlo, Ki a ma se ba wi pe o nse ofofo.

Ori ekute ile, ki se ofan o, ewe oniyeye, ori odẹ, ori awoko, epa oboro, etutu eran esin, ata oluweri ohun ti a npe ni ata oluweri yi eso awerenpene ni je be, a wa jo gbogbo re po, a wa ma fi fo eko tutu mu, a si ma ta oyin si.

itieni, Irun abiya akuko mejeji,

12. Akara, Irun ori ti eni, kuluso meta, a wa jo gbogbo re po. a wa fi te ifa eji ogbe a wa sin gbere metameta ni abiya mejeji, a si la iyoku.

13. Abẹyọ ọgede, ile agbon ile, odidi atare aja kan, ekanna owo eni, ekanna ese eni, a wa jo gbogbo re po, a wa fi sin gbere lori, gbere laiya, a wa ma la iyoku.