Ogun iba

1. Egbo ilera, egbo ifọn, egbo ipapo, egbo ọpẹ, egbo ako ibẹpẹ, àlùbósà eléwé, ẹru awola, a o gun gbogbo rẹ pọ, a o wa popo mọn ọṣẹ, a o maa fi we omode ati agba, I baa se orẹrẹ, ibaa se iba, gbogbi nkan wonyi ni o ka

2. Egbo-orombo were, ewe orombo were, egbo abo rere, ati ewe rere, ogede were dudu, ata dudu, alubosa elewe, iyo, a o gun ni agunmu ao ma fi muko gbigbona.

3. Ewe lyeye, ewe emilẹ, ata dudu, iyo, iru, eru awola, ao gun ni agunmu a ma fi mu eki gbigbona.

4. Ori-elulu, ori aparo, Imi orun, etu ibon, alubosa elewe, eru-awola, a o gun, a wa po po mo ose, ama fi we nigbagbogbo.

5. Ewe emile, ewe-elu, ewe-ewuro, Ose ao gun gbogbo re po a ma fi we.

6. Ewe Ijan, ewe la pupa, ewe igi ita, ewe oruwo, ewe oruru, Jankawo, eru awonka, aose ni agbo, a ma fi we nigbagbogbo.

7. Isu aidan, eru awola, ile eiye, etu ibon, ao gun mon ose, ao ma fi ose na we nigbagbogbo.

8. Isigun, ewe orombo were, omunu ewe asunwon, ehu ile die, eru awola, baka die, abere, ao lo gbogbo re a fi iyo si, a wa ma fi fo eko gbigbona mu.

9. Omunu oruwo, ewe awẹdẹ, egbo atare, oburo, Igi taba tutu, ao se ni agbo, ao ma fi agbo na we

10. Etiponla, ewe atare, ewe ọgẹdẹ odo, ewe orombo were, ewe kakasenla, a se ni agbo, ao ma fi agbo na we.

11. Ewe agbasa, egbo rere, ẹru, Isu Aidan, lyere diẹ, Iru ao gun gbogbo rẹ po, ama fi mu eko gbigbona.

12. Tiro die, etu ibon die, ewe orombo were, efinrin, wẹrẹ aidan, ewe agbasa, ata dudu, Iyo, a o lọ, ama fi mu eko gbigbona nigbagbogbo.

13. Epo ọgano, Egbo Sapo, eru awola, ewe orungo ao se, ao ma fi we, a si ma mu

14 Ewe ewuro, ewe efinrin aja, ewe lapalapa pupa, ewe koleorogba, a wa se gbogbo re po, a ma fi we, a si ma mu.