OGUN IKO

OGUN IKO

Ogun iko yi je ogun pataki ti gbogbo aiye ko ti mo, orisirisi iko ni a le fi ogun yi wo gege bi iko T. B, iko ti o gbẹ, iko tia npo eje ati iko ti a finbi nkan ti aje mo onje ti a je.

Lo ogun yi wo iwo yio Si ni ilera nitori ara lile ni ogun ọrọ

1. Asin mewa, oga mewa, iru oni sile Kan, etu ibon, ewe iyeye, isẹta, nta dudu, alubosa elewe, a gun a fi kanhun ati obuotoyo si, agunmu ni

2. Oro adete lopolopo, ewe patanmọ lopolopo, alubosa, iru lọpọlọpọ, epo, iyọ iyere, obuotoyo, ori, ao se gbogbo re po, o dara pupo ki e ma gbagbe gegebi mo tise kọ. Ikọ asi ma mu enia wu lowo lese ogun re ni o

3 Egbo aka, egbo isepe agbe, egbo asunwon, baka, alubosa, orogbo 9, atare 9, iyere, afara oyin-igan, aidan, korofo-eyin adie, imi orun, jankawo, isigun, ao gun gbogbo rẹ po, ama fi mu ẹkọ gbigbona.

4. Orogbo gbigbe, etu ibon die, ifofo okun, a wa lo gbogbo re po, awa te ni ejiogbe.

OFO:Akowu, akowu akowu, kogodo, ko re le yio ku keresekese, o difa fun orunmila, yio fiko gba ọmọ ologo lọfọn, nijo to je gbese egbejo oke, won ni ki o to lo gba owo hun, won ni a fi bi o ba mu gbese ti mbe lorun omo re kuro, o ni on yio san, o wasan owo na tan, ni iko ba lo ile re, ki iko lo ile re lonio (3 times) la wa ma bu sinu epo tutu awa ma la.

5. Ẹrẹ odo, huhu adie dudu, ti ko ba ni ami a wa wa, egbo erin, a wa pa pepe, a wa yo igi inu re, a o gun yio kunna, ao jo huhu adie ati ere odo yi ni o, a o wa toju oyin ireke, a wa fiisasun titun se, iyerosun la fi te ifa ejiogbe

OFO: Iko ni se omo oba kefun, kelebe ni somo rija-ile, opake ni se omo Olodumare, iko ti se omo oba kefun, won ni omo oba kefun ku, won ni kio ma jogun tire, kelebe ti se omo arijale, won ni arijale ku, won ni kio wa pin ogun tire, opake ni se omo Olodumare, won ni Olodumare ni ki ku, won ni ki sa, ise Olodumare ni eniti iwo mbe lorun re, kuro nibe.

6. Ifofo okun, kanfo, ati alomu die, korofo eyin adie, ao lo, a fi ẹtu die si, a wa da sinu oyin igan, oluware yio ma la.

7. Oyin igan, omi orombo were, epo die, suga, a wa po po, awa ma la si iko na.

8. Suga epo ata wewe, a o lo ata nani, oyin igan die, ao ma la.

9. Kafura, omi sukusuku ogede were, ao lo abere, sasangbaku, eso eSe agutan, eSe agutan yi ni awon obirin si finpa kolo alo gbogbo re, awa ro sinu igo, omi sukusuku ogede yi ni omi re, awa ma yo omi re mu diedie.

10. Etutu ẹkan, a o lọ yio kunna dada, a o ma bu sinu epo, a wa ma la si iko na yio si fun ni alafia.

11. Ẹru awola, ao lo yio kunna dada, ao toju oyin gan ao lo alomu die si, oluware yio ma la si iko na.

12. Epo-oruru, a o gun yio kunna, epo-ira, awa mu ogede a sa iti re, a wa gun ninu odo, a wa fun omi re, sinu igo, oniko na yio ma mu.

13. Epo oruru, ewe omisinmisin, eso ogede were, a o se ni agbo, yio ma mu, yio si ma fi we.

14. Tẹtẹ elegun, ewe gbegbe, ewe omisinmisin, ao se, eleyi je agbo mimu fun oniko na

15. Egbo-ipin, tete elegun, ẹtu die, ao se ni agbo mimu ni.

16. Egbo ekan, egbo-ipin. egbo ọpọtọ, eru awonka kan, ao se yio jinna, oluware yio ma mu si iko, iko na yio si kuro nibe.

17. Etu ibon, Tangiri, ao la tangiri yi wewe ni, awa ra alubosa elewe lopolopo, a wa ko sinu oru, awa bu omi le lori, oluware yio ma yo mu diedie.

18. Omi orombo were, kannafuru lopolopo, oyin igan, a wa lo kannafuru, a wa ro gbogbo re sinu igo, a wa ma mu diedie.

19. Ao lo obi gbanja ti yio kunna, ewe gbegbe, ao se agbo, oluwa re yio ma mu lemeta lojojumo.

20. Odidi adie kan, eran etu die, eran ewure die, ewe omisinmisin gogoro, osibata, eri ogi, obuotoyo, etu ibon, ori, adi, epo, awa lọ gbogbo re po, a fi se awon eran wonyi je, nigbati o ba je obe yi tan, yio wa lo fo isasun re si oju ona ti ko ba ni to titi odun meta, sugbon ni Ojo tio ba gba ibe, ni ojo na ni yio tun gbe iko yio.