OGUN IDADURO

OGUN IDADURO

Bi obirin ba se alejo pari anlo ogun yi, bi obirin ko ba si ri alejo re loni, titi di ojo keta, a nlo ogun yi.

1. Ilẹkẹ ati otutu ọpon, ao sin ni dede ikadi, ewe-arojoku, eran ewure, ao lo iyere si, bia ba ti fe ni ao ra eran to, a wa ka ileke yi a fi tele isasun, ki ato se obe yi, nigbati o ba jina tan, obirin yi o kọ pọn ilẹkẹ yi la na, yio fi bo idi ki oto je obe na, ojọ ni aje obe na tan o.

2. Ori ikun, atare kan, oju oro lopolopo, a wa jo gbogbo rẹ po, a ma fifo eko tutu mu ni aro ati lale.

3. Ewe ailu, emọ agbo, ewe alupayida, odidi atare kan, ao jo gbogbo re po, a ma fifo eko tutu mu.

5. OBE:-. Ewe agidimogbonyin,a fi pepe re, egusi, ao se ni obe, obirin yi yio fi ojo marun je, nigbati o ba nse alejo lọwọ, nigbati o ba pari ko ni je obe na mo.

6. Eku emọ, ao fi oje emi si eku emo yi daradara, a wa toju iyeye ati epo, a wa se ni obe yio jinna dada obirin na yio ma je

7. A gbo ewe-esisi ti yio po, a wa gbe pamo si ibi kan, nigbati oba di ale, ọkọ ati iyawo re yio fi taba, a kimuo.

8. Eyin adie tio ba ye ni ojo, odidi atare kan, emo agbo, awa jo gbogbo re po obirin na yio ma fifo eko tutu mu.

9. Osekelenje alamu, ao ge owo otun re, ao mu eyo atare mewa, ida-oju bata, owo ero ẹyọ kan, a o ran owu ao so mo lori ati niidi, awa se ni onde elesun, obirin na yio wa bo si iyara tio ba ni ilekun, yio wa bo aso sile ni ihoho, yio fi owo mejeji ti ilekun na, lati sode, titi oko re yio fifi onde yi bo nidi, ko gbodo bo titi yio fi di ojo ikunle