OGUN GIRI

OGUN GIRI

Giri jẹ arun ti o ma nda ẹda ni amu, ati Ọmode ati agba ni si mu.

arun yi ni si mu ẹkẹ enia wa, Ẹniti o ba si mu ko ni ri igbonse se, a si ma ma so opolopo di alabuku, Ogun wonyi si kapa girina.

1. Igitaba tutu, tangiri, ao jo, a wa ma bu sinu adi, ao ma la, asi ma fi mu eko gbigbona nigbagbogbo

2. Tangiri, ao be epo ara re kuro, a wa re si wewe, alubosa elewe, epo, adi ati ori nia fi se ni obe ti yio jinna dada, oluware yio ma je nigbagbogbo.

3. Eso akerejupon, ao jo awa ma fisi adi, lila ati pipara ni o.

4. Ao toju oruka dudu bi adota, alabahun kan, adie opipi. eiyele kan, ewe agbasa, ewe isepe agbe, egbo ẹni ore, igbin kan, a wa lo owo awon ewebe, a wa wa isu ogirisako ti o ba tobi, awa da ni pansa, a wa ro eje eiyele si, a ro eje adie si, a ro eje alabahun si, a wa ko oka yi si, a wa ko ewe ti alo yi si, ni a wa fi Omori rẹ de, o si di ojo kerindilogun, ama fi bo owo

5. Ekolo lopolopo, eyin adie tutu mewa, alubosa elewe, a o lo gbogbo re po sinu isasun, epo, ori, adi, a wa ma fi pa ara, eleyi jẹ ipara tutu.

6. Ewe taba tutu, alubosa elewe, obuotoyo, ifun adie, ifun olonginni, adaripon kan, ose die, a wa ko gbogbo re sinu kongo, adi eyan, ori, a ma laa a si ma fi para eniti giri ba nda ni amu.

7. Egbo sajere, egbo ipeta, egbo ifon, egbo-ogbo, ao ge gbogbo re kekeke, adi, ori, epo, a wa se ni asejo, nigbati o ba tutu, ao wa gbogbo egbo, igi yi danu, awa ra alubosa, baka, oronro malu, asin, oga, awa gun gbogbo re po, a wa da po mo asejo yi, ao ma ja, a si ma fi pa gbogbo ara.

8. Obi gidi lopolopo, alabahun kan, Ipepe aka, ipepe ore, egun ori obo, egun efọn, egun erin, ewe iyeye, ewe saje, ajo gbogbo re po, awa te ni ejiogbe.

Ofo Ipa ki pa omo erin ninu igbo, egba ki gba omo efon leluju, ewo orisa, a kita ipe orire, ko pa omo obo lori igi, ipa ki jahun, ọrere ki je ewe iyeye, idayin ki je ewe osanwewe, a wa fi adi si, a ma la, a si ma fi para.

9. Alangba kan, ewe rinrin, ewe abamoda, odidi igbin meta, egbo awusa, a wa jo gbogbo re po, a wa fi sinu adi, ao ma la.

10. Asin kan, oga kan, ojuoro, osibata, a lo gbogbo re po, ao fi sinu osun, a ma fi para,

11. Ilako kan, igbin kan, ipepe irin, a wa gun gbogbo re po mo ẹtu, a wa po po mo ọse, a ma fi ọṣẹ náà wẹ

12. Odidi olongbo, ori agilinti kan, ao jo po, pelu odidi olongbo yi, orogbo meta, atare meta, a ojo gbogbo re po, ori pelu epo, a wa mala

13. Epo afa, egbo ifon, egbo ipeta, alubosa elewe, adi die, a wa ma fi se agbo, a ma mu, asi ma fi we, agbo omode ni o.