OGUN FADUFADU

OGUN FADUFADU

Arun na nigbati nkan ba fe le jo si obirin lara, ni arun yi yio dide ni odo abe obirin, géegebi igbati ejonu nrin kiri gbogbo ara.

Bi iru arun yi ba mu Okunrin, igbehin re inu yio ma run, gbogbo iha ni yio si ma ro, yio si ma wuko pelu, be si ni bi obirin ba nri nkan osu, bi iru arun be ba mu obirin, iko ni yio si gbehin re. Ohun ti asi le lo ni wonyi

1. Itan etu, egbo ewe ẹtu, eso opele, egbo sajere die, awa lo gbogbo re po, a wa fi se itan etu yi, epo, ori, adi, obuotoyo, a o se yio jina, eni na yio ma je obe yi.

2. Egbo-ajalugboọgan, epo ponhan, epo-afara, alubosa lopolopo, ẹru awola, ao se ni agbo yio ma mu, yio si ma fi we.

3. Aran ọpẹ ti ko ba ti yo ninu iya re, epo aworonso, ogede were ti ko ba ti gbo. A wase ni agbo gbigbona, oluware yio ma mu yio si ma fi we nigbagbogbo, nigbati a ba bẹrẹ si lo awon agbo wonyi, ao si ri iyipada arun na.

4. Ifun ọka, ifun ọrẹ sẹsẹ, epo odo iya, iru, alubosa, ata were, iyọ, awa gun gbogbo re po, a ma fi fo eko gbigbona mu.

5. Epo-ayin, epo-idi, egbo-asunwon, egbo-koleorogba, egbo arunjeran, a wa pa gbogbo re pepe, kanhun bilala, ata eru, alubosa elewe, a wa gun gbogbo re po, ama fi mu eko gbighona.

6. Eku eda kan, omunu papanla, ewe-aiku, ori, epo, ao se ni obe a wa ma je.