OGUN EHIN (back)

OGUN EHIN

1. Ewe ehin olobe, oko-atare kan, ao lo awon nkan mejeji yi po yio kunna, a wa fi te ogbe wehin, a wa ko si ehin igbin, ehin igbin yi si nia ti te ifa na, a wa fi sin gbere si ehin, awa so igbin na sinu igbo

2. Ehan, irun oruko, ao Io yio kunna, odidi atare kan, ao lo po mo ehan irun oruko, a wa fi sin gbere, si ehin, kokọ okunrin, beni ko kọ obirin.

3. Ogangan enu gbasoro owule, ao ke panti die nibe a fi odidi atare kan si, a wa lo gbogbo re po, a wa po mo ori, a wa ma fi ra gbogbo ogangan ibi ti ehin na ba gbe ndun wa.

4. Egun ẹhin esin, egun ẹhin ọka, odidi atare kan, a wa jo awon nkan meteta yi po, a wa fi sin gbere si ogoro ehin, a fi die sinu ori, a ma fira ehin, a ma sin iyoku ni gbere nio.

5. Ehin olobe, egun ehin oka, odidi atare kan, awa jo gbogbo re po, a wa fi sin gbogbo orun ese mejeji yipo, ati ogoro ehin.

6. Ehin olobe, ao lọ yio kunna, ila kan, a wa fi pẹpẹ rẹ, iyere, igbin, pẹpẹ la fi re igbin na, ori si ni a fi se epo re, a wa ma je fun ehin na, ko si eniti ko le je obe na, ati omode ati agba, ni yio je obe na

7. Oja Ikoko, ao gun oja ikoko na, ao po okun odan eki, a mu oja ikoko, a fun obirin nigbati a ba ba lo tan yio fi nu abe re, okunrin na yio fi okun odan eki nu tire na, a mu iko ode meta, ama ya teretere, ama fi kun okun mejeji yi, a ma fi ran onde, bio ba se okunrin ni, a o ta onde na ni koko mesan, bo ba se obirin ni ao ta onde na ni koko meje, awa fi ran onde si idi pelu awo dudu.

8. Ewe kenke, a o lo yio kunna, ọkọ atare kan, a wa lo gbogbo re pọ mọn ori, oluware yio ma fi ra ehin.

9. Etu ibon, eri ara opo, egbo-ewe toto, a wa lo won po dada, pelu oko atare kan nia o lo ogun yio, a wa sin gbere kokan ni atanpako ese mejeji ati gigise mejeji fi sin gbere ni ehin na,

10. Gbogbo oju-ona, odidi atare kan, igba ehin alababun, ao jo gbogbo re pọ, gbere si ehin, ao po yoku mo ose wiwe ni.

11. Aha ọwa tio gun to ni, eyo atare 9, ao lo po gbere si ehin.

12. Eku ago kan, opa ti won fi de ebiti, ewe ehin olobe, ao jo po, gbere ni ehin.

13. Owu ọrun, ti won fi gbọn owu, a fi ran onde si idi.

14. Igbin apinnu kan, owo ẹrọ meta, ewe ehin olobe, awa fi pepe re igbin yi si merindinlogun, nigbati a ba bo tan, a wa lo gbogbo nkan wonyi, a wa fise igbin na, enitiehin ndun yi yio ma je.

15. Gbongbo ipin, ao bo okun rẹ, irun iru esin ao ran ni onde si idi, a wa ta ni koko, bi o ba se okunrin 9, bio ba se obinrin 7, a wa ma fi si idi nigbagbogbo.

16. Egbo ọdan ẹki, a o bo okun re, a wa ya iye igun, a ya iye akala, a wa ma fi esọsọ fi atare si titi yio fi pe 23, a wa ran awon nkan wonyi po mon ara won pelu Ata mesan yi, a wa firan onde, pelu awo dudu, a wa ma fi bo idi.