EBE AWON AGBA

EBE AWON AGBA


Olorun ni o le bẹ won o, ise ti won nse. si ara Eda ko kere, nipa ki a ma je ka ni owo Iowo, ati nipa ki won o ma je ki abimo; nipa ki won ma je kia sun loru, ti a ba roti enia, aiyele su ni nitoto, ogun yi wa dabi enipe omode meji nja, ti agbalagba nkegbe mo won, gege be ni ogun wonyi ri fun awon eleiye

1. Aya ọsanyin 16, ọsẹ sile mẹta abo 3/-6d, idaro agbede, ao sun idaro yi ti yio pon, a silo ti yio kunna dada, ewe ajeobale, a gun ewe yi yio kunna gidigidi, awa ko awon ewe yi sinu odo, a wa toju oruko tio ba ni irugbon, a wa ro eje Oruko yi. sinu odo, eje Oruko na ko gbodo kan sile, a wa po mo ose idaro ati ewe ajeobale tia gun yen, A wa fi ori oruko yi tele inu igba, a wa ko ose yi le lori; a ma bu ose na we, a fi osanyin 16 gun ose lori, osanyin onirin, e simo pe ose yi kapa awon agba, O dara fun aboyun pupo titi tiyio fi bimo.

2. Akuko adie opipi, iko odẹ 10, a fi epo ra adie yilara, a wa lo fiko ijalo, ewe ‘ajeobale, epo-obo, iwerenjeje 200, ido 200, yerepe lopolopo, odidi atare kan, a wa jo pọ mo adie yi, a wa te odu ifa osebara Si, ati ewonrin meji

Ofo: Ṣekete beu, ọjabẹbẹ, alasọ funfun ona ọyọ, sẹkete beu la pe ifa, ọjabẹbẹ la pe esu, alasọ funfun ọna ọyọ loruko ti a pe iyami oṣoronga, a ma fifo eko tutu mu ni ososu.

3. Odidi okete kan, agbo kan, a pa agbo yi, ao ro ejere sinu awo kan,a wa fi ori tele ikoko tia fi jo ogun yi, egungun janduku ni yio ba ni pa eran na, a fun egungun yi ni owo, yi olo ba ni pa epo oruru ase ale ati ti aro, ati ase ale ati taro apa, ati ti iroko pelu, igo adi ẹyan 2, a ma ta si diedie, nigbati a banjo, egungun yina ni yio ba ni jo gbogbo ogun yio. Odidi atare 16 ni a dasi o, a ki si jo ogun naa ninu ile, inu igbo lati jo o, Egungun yii ko gbọdọ fọ ohun si enia a fi ohun egungun‘ni yio ma fo titi yi ofi jo ogun na pari.

tia ba wa egungun ti yio ba ni jo, tia ko ba ri, awa gan gan na le se nkan yi, sugbon ohun ti egun ni a ma fọ nigbati a ba nse awon nkan yi, tabi bi a ba ri aso egun die ti a ba jo mo ogun yi ko si iyato nibe, a je wipe egun na lo jo niyen. Nigbati a ba fẹ jo tan, ada kongo ata kan si, nigbati o ba tutu awa te ifa yi owonrin esinja, bi a ba da oruko ifayi, a fi epo ba enu, ki e bi awon babalawo lere odu ifa na, babalawo yio si rohin odu ifa na fun yin. Elo wo odu ifa mi amulu ti ki si oju odu 16.

Ofo: Ata-ngboyin mo ni kokoro 3, ikokoro moni tangbonyin 3, ati di wewu ogun ja apa 3, lo difa fun alantata 3, a bi obo jojo 3, ti nko won lo si igbo idoko 3, nigbati yio de be won ni ki ni ẹ ba, won ni awon ba okete alara jonjo, iyami osoronga ni ki won o pa, won ni ki won o bo awo re ti oju ti imu, won ni ki won o fi da apo amininjekun, ko ti inu apo amininjekun ko bo sinu alahunhuntan, ko ti inu alahunhuntan ko bo sinu alahunhuntahun, iyami osoronga won wa pade awon odimodimo, won lẹ ti da, won ni to ba ku meji awon a taji, won ni bo ba ku ikan, awon a ta kan, iyami osoronga ni ki won o pa won, awon a fi fere sinu fon finfin, won fon imu otun ferere, igba eiye bo, won fon tosi ferere, igba bo, ifa lo nse tan ti on yio roro gbayi, o ni e mọn o n owonrin esinja, eko beru on kie si wa ba ti ara orun pelu, o letiri tie fi nfi esuru pe esuru, tie fi nfi esuru pe esuru, bi omode ba dari kan oruru, oko ni won ti ru oku re wale o.

Ogun yi aro sinu akerengbe, alu ni idi a si lu lori, ninu osu ti a jo, ati enu bu, a fi fo eko mu, ni osu keji a ti idi bu ogun yi a si tun fifo eko mu, ipa agbalagba ni o ka ogun yi, lilo re ko ko omode o.

4. Adiẹ opipi kan, ewe-ajeobale, isu ekuru 3, a o jo pelu odidi atare kan, bi a ba jo ogun yi tan a wa te ni owonrinrosun,

Ofo:-. Ododobale se gbarangada, akiri poro ehin oloran ki inu oloran ma yo, o difa fun orunmila, ifa ji ninu olubi, ifa sun larin olubi, adie opipi ko ni apa imufo, eye keiye eroke, e lore se si, ama fifo eko tutu mu.

5. Aso egungun, Ewe-ege, ewe afẹloru, epa imi gbigbe, itawere-iru, eku-asin kan, epo obo, a wa jo gbogbo re po dada, a wa te ni iretewori

Ofo: Eiye keiye ki je eso ege, eiye keiye ki je erun, eiye keiye a ma ku aramu, a je ki roro ko je erun, iwo ko gbodo je omo aladi, a ma to si ori, a sima fifo eko tutu mu.

6. Dagunro wẹwẹ, eyin adie meta, iko-ode meta, a wa jo gbogbo re po, pelu odidi atare kan, alo yio kunna dada, ama fifo eko tutu mu, osi dara pupo fun awon ti ba nse are, ti won si nla ala nigbagbogbo, a si po die mo ose, alamodi na yi o fi ma we, were ni alafia yio si de fun eni na.

7. Ewe-bara tutu, a fi pepe re si were, a fo eyin adie kan si, a bo igbin kan, a ware si 16, a wa din ni obe.

Ofo:Elaro wa, emi ni npe o, igunnugun ra ba lori ile, adie yẹ gẹrẹ ni sare, odifa fun bokinni orun, a bukun taiye ye, bokinni orun, wa bukun taiye, egbe aiye e wa bukun ẹgbe orun, e wa bukunmi, ao ma je ọbẹ naa.

8. Irun ori eni, ao fa, atu ebogbo huhu akuko adie nla kan atoju kerengbe tio bafo si ona odo, alakan 1, a wa jo gbogbo re po, ejiogbe ni odu ifa re

OfO: Ọba lomogo aiku, nla npe ifa, oba lomogo imi lese, la pe odu, alamo ti nmo ori, la pe orisanla, a la pata ekun so won la pe esu, e wa jọ mi si wa yi, bi eruko ba ya asin lehin oko, bi akeregbe ba fo, asin leyin odo, oju kipon ori, kio ma le hu irun, oju ki pon adie gogoro kio ma le hu iye, eni ba wipe on yio ri iseju alakan, oluware yi o ba eri lo, ama fifo eko tutu mu. |

9. Iku-Jjebu, epo-obo, ewe ajeobale, ewe-awede, eso yerepe, a o jo sbogbo re po dada, a ma fi fo ẹkọ mu.

10. Ewe egele, ewe awon ekun, ewe ora, ewe ajeobale, awo ewiri, awọ ẹkùn, eyin adiẹ 10, Iko adie 10, odidi atare 10, a wa gbe pẹpẹ oro 10; a wa jọ gbogbo rẹ pọ, a ma fi ẹkọ tutù mu.

11. Ejigbede eiye ega, a fi Iko ode bo ni —oju -nti okokan, odidi atare kan, a 0 jo won po, a fi sin gbere, meta ni aya otun, mefin ni aya osi, merin ni ehin otun, meta ni ehin Osi

12. Iko owu-dudu kan, eiyele kan, ewe-ajeobale, ori igun kan, eyo orogbo kan; ewe-tannaposo, asin kan, oga kan, edun ara kan, ewe munimuye, a wa jo gbogbo awon nkan wonyi po, awa lo edun ara yi ti yio kunna dada, a wa ro sinu atọ, apa alabahun kan, afi eje re yi ato yi, ama fifo eko tutu mu.

13. Isu ekuru 10, eiyele kan, ewe mafowokan omo mi, epo egusi ti won ba se larin oja, ati ajeku ireke arinoja, ewe iku-pero, a o jo gbogbo re po, a ma fifo eko mu.

14. Ewe-ajeobale, ewe ata tabi ewe ilufemi, ewe akerejupo 200, epo-obo, egungun ẹkun, ewe birana, on na ni a npe ni omini, isu elu 3. A ge ori ọpa a ro si, awa jo gbogbo re pọ, a wa po pọ mo ose, a ma a fi we loru, a ki lo ni osan o.

15. Omole, iko-odẹ, ikakure, okan pepeiye, oju oro, Osibata, ewe lapalapa pupa, ewe-agemo ogun, odidi – atare meji, iru (toro) a wajo gbogbo re po, a fi sin gbere si orikerike gbogbo ara‘

16. Obi-ifin kan, obi ipa kan, a wa bo mo oritameta, alo re wu kuro ni ojo keje, a wa ra adie opipi kan, ayo okan re kuro, a pa po mo obi mejeji yi, atare aja kan, awa jo gbogbo re po, a fi sin gbẹrẹ kokan ni gbogbo orikerike ara, awa fi adie yoku se sara.

17. Ti amodi ba nse enia ni ede, obi ifin kan, obi ipa kan, ao bo mo enu ona, a fi eyin adie kan si, eyin na ko si gbodo fo, ewe kohin sorun a fi meje le lori, a wa bo mo ile ibiti a gbẹ

18. Ewe-iroro, a si npe ni roro, a o gbe ile ni yara, a ja ewe yi yio po a fi te ile a fi eyin-adie kan si, a fit iye- rosun te ifa ejiogbe, a wa bo mole larin yara ko ni ọfọ.

19. Ere sile ewe ajeobale 200, eyin adie 3, aso osun die, ao j o, ao fi te ifa osameji

Ofo re: A toju obi gidi oloju merin a wipe olalekun, ominikun, atatankun, iwaju okun okun, ehin okun okun. o difa fun orunmila, baba mbe larin ota, ohun tio ba wu ni, a wi si ni adura fun ara eni.

20. Koropo were lopolopo, odidi atare aja kan, epo obo die, ao jo, a te ni osameji, a ro sinu ado, nigbati a ba fe ma we, a ma ta sinu omi

Ofo:Omo oloro nie be jẹjẹ be jẹjẹ, omo oloro ni ẹ bẹ kunkun bẹ kunkun, o difa fun orunmila, ifa nbe ni gba te mu aiye gidigidi orunmila ni bi o ba je wipe bi ti on ni, o ni bi omi gbigbona ba da po mo tutu, o ni Olorun Oba niba ni yanju re, o ni bi omi gbigbona ba da po mo tutu oni ifa na a ma ba ni yanju re.

21. Ẹgun sango, egbo iroko die, ebo ti won baru si idi esu, a gbe ẹbọ na, ewe ẹgẹlẹ, ewe-aragba, soso-eyin, iku ijebu, ata pupa, ao jo gbogbo re po mo odidi atare aja mefa, a wa po po mo ose, ama fi ose na we.

22. Opolo ijokun, egbo ẹgbẹsi tutu, egbo ijokun, ao gun gbogbo re po, apo po mo ose, a ma fi ose na we ni igbagbogbo, ko ko agba ko ko omode.

23. Egbo tannaposo, ao jo pelu odidi atare kan a wa ro sinu ado kan, a sin ni gbere kokan ni oju mejeji, ada die sinu adi ati osun eni na yio fi ma para.

24. Egbo-ope, ewe-ajeobale, ao lo yio kunna, a wa sa yio gbe, nigbati o ba gbe, a wa fi te ifa osameji, a ma ta si ibi igberi wa, tabi kia ta die sinu omi, ‘ka fi ju ita ni alale ka to sun.

25. Isasun tuntun, igbin kan, eiyele kan, ewe-boboawodi, oruka-ide 20, oruka baba 20, oruka oje 20, oruka irin dudu 20, ewe owo, ao lo gbogbo ewe yi ni

a o ko sinu isasun, a wa lọ bo mo ibaluwe nigbati o ba di oju ogunjo, a wa lo wu, enikeni lo le fi bo ọwọ o

27. Poporo oka ti o ba ka odun, poporo agbado ti o ba ka odun, ewe-egele, ewe-awonekun, a bu die lara yangi esu, a wa jo gbogbo re po, a jo pelu odidi atare meta, a fifo eko tutu mu.

28. Igi nla die, epo obo lopolopo, ewe-tannaposo, ewe-egele, ao ko gbogbo re sinu ikoko, a pa adie opipi, ao ro eje re si, a si so ori re si, a wa fi iyerosun te odu 16, awa da si a wa gbe ikoko na ka Ori igi alaketun meta, ko gbodo kan ile

Ofo:Iku ni se olohun oro, ogbigbi ni se olohun aro, o difa fun Orunmila, o n sawo lo si oke odo sopo, nigbati yio de be o ba pataki ori, o ba gege-aiya, o ba kukulaku idi, oni o n yio wi ni ile, won ni ma wi nile, iku fi ile jin mi, arun fi ile jin mi, ofo fi ile jin mi, a ma bu, ama fi we, aha kakamisin la fi bu, a ki fi gbademu bu o.

29. Agbo isinle ebe awon agbalagba, a o ra ako aja kan, a oke ori re tele ikoko, ara agbo kan, a ke ori te tele ikoko, alabahun kan, ori oka, ori-sebe, ori abiru soro, ao ro ofa meje, a wa ko gbogbo re sinu ikoko, a wa ja ewe akoko, ao gun, awa ko le, a wa tu garawa epo kan si, a wa te gbogbo odu-merindinlogun (16) awa da le lori, iyerosun la fi te ifa re.

Ofo re: ẹlẹyin gerin, aringindin gẹfan, aloro lo bi aja, ofikilo bi adie, o ba alagbede ja te omo owu fo lo bi sanponna, alagbede ojo kini, on loro igba igbin bo igbin, on loro igba ahun bo ahun, on lo ro ewu oko sile de ejo, on ni o ro ofa fun sanponna, ihoho ni omo alagbede Imoba ojo kini wa, a wa yangi esu nla kan le ori koko agbo na, ama pa igbin si ni ododun, ama fi we, ko si ohun tia ko le lo agbo yi fun.

30. Ori sebe, epo obo, ile-agbon ile, odidi atare kan, ao jo gbogbo re po, a fi sin 40 gbere, ni ori.

31. Igbin kan, ewe kinlafimise, epo-obo die, a wa re igbin yi Si 16, ewe koko tia fi se obe a wa se ni obé, a wa fi iyerosun te ifa osalu-fun-ogbe

ofo: atoju je ni, a ti aiya je okan, a ti ipenpeju je oronro, ati -oju je ni, nlo bi akoda sotun, ati aiya je okan nlo bi akoda si osi, a ti ipenpeju je oronro, on lo bi akoda Si ona koro kanga, a wa fi se obe na je.

32. Bante, a wa na owo sinu ikoko aro, ọwọ yio de ile re, a wa bu ekusu aro, asi lo bu irawe odo adagun, odidi atare kan. a wa jo gbogbo re po dada, a wa te ni osabara, ama fi fo eko tutu mu nigbagbogbo.

33. Ewe koko ti a fi nse obe, ewe egele 16, abere ide 3, oruka idé 3, a wa toju igbin kan, asi ge igbin na si 16, a wa lo gbogbo ewe yi ti yio kunna dada ori ni a fi se obe na, abere ide ni a ma fi gun igbin yi ti a ma je nigbati o ba jinna, a wa ma lo oruka meteta ti a se mo obe yi.

34. Eiye ologesa kan, eiye ega kan, Iko ode meta, odidi atare kan, a wa jo gbogbo awon nkan wonyi po dada, a wa ro sinu ado, nigbati a ba ro sinu ado tan, a si di ado yi ni enu dada, a wa fi ado yi bo inu imi tia ba su ni aro, ati imi ati ado a wa tun jo lekeji, awa ma fi sin gbere ni orikerike gbogbo ara patapata, o dara pupo fun alamodi, lati sin ni gbere, ati wipe ko ko enikeni.

35. Ido 200, lowerenjeje 200, a se obi ifin si 200, obi ipa si 200, Iko ode 7, iye. aluko 7, odidi eye ase kan, eyo atare 200, aso ara ipade, ao jo gbogbo re po a ma fifo ekg tutu mu nigbakugba. O si dara fun alaisan ti ba nla ala, a si sin gbere si orikerike gbogbo ara ni eyo kokan

36. Eiye ega 7, eiyele kan, igba koro isin, igba eso apa, igba ido, eso yerepe, kongo ata wewe pupa kan, a wipe ki awon omo kekere ki won mu okun ki won o fi di bara meta, nigbati won ba didi di ti won ko ri di, a wa mu kan nibe, awa ge okan na si I6, a wa ko gbogbo re sinu agbada, ako gbodo jo ogun yi ninu ile, inu igbo la gbe jo o.

Ofo: Eiye kekere a bi ohun hara horo, eiye kekere a bi ohun musue, obo merindinlogun ni nbe lode orun, sebi omolomo ni e fi pajẹ, e ko gbọdọ pa enmo je, ti e ba pa enmọ je, elenmon ko ni jeki e gbele, Olodumare ko ni je kie gbe ode orun, baraka, baraka, baraka, lode orun bara, eni ba pa mi, barabara ni yio ma ba kiri, bi aje pami, bara loran re da, balufa pa mi. Eni ba lo ogun yi, bi ole ko ile re, tabi won fi nkan ijamba se oluware yio ri eni ba se nkan be. Ogun na dara pupo.

37. Isawiri 16, ori aja tutu kan, igbin kan, oluogan kan, ata pupa, iwerenjeje 200, Awo lili, odidi atare mefa, odidi erin agbado omonla pupa, a ge die lara opa aro, a wa jo gbogbo re po, a ma fi fo eko tutu mu ni igbagbogbo.

38 Akere merin, oga merin, asin merin, okete kan ti. won ko ba tu ifun re, awon Oju egun, ewe agogo-igun. Ewe bobo awodi, ewe ajeobale, a wa jo gbogbo re po, a wate ifa, otura oriko, ama fi fo eko tutu mu

39. Adie dudu kan, Kongo ata kan, oju oro, osibata, epo Ose, ale ati oro igi ose yi ni apa epo re, obi ifin kan, obi ipa kan, odidi meta, ao jo gbogbo re po dada, a wa fisin gbere, awa po iyoku mo ose ama fi we, gbogbo orikerike ara nia sin ni gbere o.

40. Ewe-dagunro, ewe ajeobale, agbari ọbọ, awo lili, ori oka meta, ori ejo soro meta, ido lopolopo, ao jo gbogbo re po, a wa wipe ki obinrin ko baniro eko, nigbati eko yi ba jinna, awa da gbogbo ogun ti a jo yi sinu eko na, obinrin na yio wa ro po, titi eko na yio fi le, a wa pon ni akasu nlala, a wa bomo arin odo ti nsan fun ojo meje, a wa wu ni ojo keje, a wa toju ipẹpẹ aka, ipepe ore, ewe sanyin lopolopo, opolo apola aja, a wa jo gbogbo re po ati ẹkọ yi pelu, nigba tio ba wa tutu, awa fi te oju odu merindinlogun (16) a ma fi fo eko. ao si po die mo ose a mafi we