OGUN ELA

Ela je arun itiju, gege bi ete ni ori, ti omode ti agba ni si ma mu, o si je ohun ti o yara ba enia je nitori gegebi ara igala tiri yen gan ni ara eniti ela ba mu yio se fin batabata, asi ma hun enia ju ifon lo. Ati wipe bio ba mu omo owo, tio si je jade ni enu furo rẹ, were ni omo owo na yio fi aiye sile. Ohun ti a si le lo niwonyi:

1. Agbo. Epo-afa, epo ogun bẹrẹ, rọrọ-ọdan opolopo, eru-awonka, alubosa elewe, ao se gbogbo re po oluware yio ma mu agbo na. :

2. Egbo-ewe omo, Egbo-abo rere, isu-ahun, alubosa elewe, ewe ororontohun, aose gbogbo re po, omo na yi yio ma mu.

3 Egbo arunjeran, egbo-kakaṣẹnla, epo-pandoroo, ehulẹ, alubosa elewe, adi die, a o se gbogbo re po mo ara won, yio jina dada. Omo na o ma mu nigbagbogbo.

4. Ewe iyere, ewe agunmona, ewe atare, ewe koleorogba, .egbo egbesi, egbo sigo, eru awola opolopo, A wa se ni agbo, ti agba ni eyi lati ma mu, atu lati ma fi wẹ nigbagbogbo

5. Egbo egbesi, ejinrin wẹwẹ, epo ọpọn, omi iru ni a fi se agbo yi, oluware yio ma mu yio si ma e we, ko ko omode, ko ko agbalagba pelu.

6. Ose: Iyẹfu ere, aran ọpẹ, a o sun mejeji po, a ba eeru re bi eni ba eeru aro, ao ma po omi abaje yi mo ose ati ogun tia sun, nigbati eru na ba ba, a wa ma fi ose yi we nigbagbogbo. nu ko gba irohin ose yi

7. Rọrọ ọdan, somiroro, imiorun,egbo. ipapo, eru awola, egbo-elu die, ao gun gbogbo re po mo ose, a ma fi ose na we nigbakugba.

8. Egbo-ogbo, ao ke kekeke, egbo ẹran oka, oko ofe, egbo-inabiri, a ko sinu oru, ada adi eyan sì, a o ma fi pa ara.