OGUN EHIN OMODE

1. Ewe amureju ọmunu, owo ẹyọ mẹwa, a o lọ a gun pọ mọn ọṣẹ, bio ba se obirin abẹrẹ 7, tabi okunrin 9, ni a fi tẹlẹ igba, a wa ye ọṣẹ kotokoto a fi eyin adie kan si, a wa ko ose na lori abere na, ọwọ ori ni won o ma fiwe omo na.

2. Ọgẹdẹ wẹẹrẹ ti o ba sẹsẹ yọ ni idi iya re, ao ge lori diedie, bi o ba se okunrin ni mesan, bi o ba se Obirin ni meje, ao toju ila kan a gun gbogbo re po mo ose, ori nikan ni ama fi ose na we.

3. Awọ-lili, ori-agilinti, ao jo mejeji pọ, a wa po mọ ọṣẹ, bio ba se obirin abere 7, tabi okunrin abere 9, nia fi gun ose na lori, gbogbo ara ni a ma fi ose na we.

4. Bi omode ba fe hu ehin, iba se ehin oke, iba je wipe o gbona ehin, Ofo yi nia ma pe si awuje rẹ, ao toju obi gidi oloju meta, a la awe meteta yi, a ma mu ọkọkan ni ojoojumọ, a máa jé Awe kan lenu, a wa ma pe

Ọfọ na bayi: Abẹrẹ ori, Abere ori, ogan lolo, oluporiti, abere ori la pe ehin, ogan Iolo la pe iwọ ogan, oluporiti, la pe iwo ikokoro, mota, moro, jiji la ji ba ehin lenu ejo, a wa tu awé obi kan ti a je yi si omo na lawujé

5. Ọfọ: Olatori yo akekere, a bi ija wara, osumare, ti ngbe oju Olorun sogo rere wa aiye Olatoriyọ la pe ehin akekere a bi ija wara la pe ogan, Osumare ti ngbe oju Olorun sogo rere waiye la pe ikokoro, Mota, moro, jiji Ja ji ba ehin lénu ejo, atare 3, la fi pe awa tu si omo ni awuje.

6. Bi o ba se okunrin abére mewa, obinrin abére méfa, a fi tele oru, epo igi elewe kan, epo sapo, tangiri kan, a rẹ si mesan, bi o ba si se obinrin a re si meje, a ta epo si pelu alubosa elewe, awa se gbogbo re po, yio ma mu agbo na, won o Si ma fi we omo na.

7. Agbo tutu ni eleyi o, A toju aberé 31, ati okunrin ati obinrin aso waji kijipa, a bu yanrin odo sinu aso waji yi, pélu abere yi, a di gbogbo ré po, a wa we ni owu dudu ati funfun, a wa so sinu oru a si bu omi tutu si, ọmọ na yio ma yo omi rẹ mu.

8. Ọpọrọ ẹkan 9, abere wẹrẹ 9, agbondo agilinti, awe ni owu dudu ati funfun dada, a wa fi bo omo na ni yrun. ;

9. Oporo ẹkan 10, abere 10, igori owo igbale 10, a wa we ni owu dudu ati funfun daadaa, a ma fi bo omo na orun

10. Onde: Igi Isẹpẹ agbe, ao ge kekeke, a ma fi owu sin a si ma fi owo eyo kokan si, a wa so agbondo Iki mo omo na ni idi, titi ti ọmọ na yio fi hu ehin, ko ni gbona ni agbara Oluwa.

11. Ose: Ori ejo eyikeyi, eyin adiẹ kan, Ẹgun sanga, Ẹgun ara igbago, atare aja kan, ao jo, a wa po mo osẹ, afi we ọmọ na.