OGUN RIRI OHUN BUBURU

OGUN IRIKURI:Riri ohun buburu tiko dara ni oju orun bi ki a wipe a ri egun, tabi, ki a ja si odo, tabi ki a pe a nba enikan je onje ni oju ala, tabi kia pe nkan nle wa lo ni oju orun tia ba se ogun yi ako ni ri be mo

1. Ao mu omole kan, a fi iko ode kokan bo ni oju mejeji, a si tun fi okan bo ni enu, yio wa je iko ode -meta, a wa jo, a fi sin gbere kokan ni oju enikeni ni o le sin nibi gbere na o

2. Imunmuna merindinlogun, oloyunbere kan, a fi iko ode kan ha ni enu, ita were iru mokanlenigba (201), odidi atare aja meta, a wa jo gbogbo re po a fi sin gbere kokan ni oju, ko ko alamodi, ko ko aboyun ko ko agba, be si ni ogun yi dara pupo fun awon omode, nitori awon omode ni sa ba ma riri kuri ni oju orun.

3. Monisẹsẹ, ikako imo osun igba olekan (201), Ikakure igba olekan (201) eso werenjeje igbaolekan (201), igba ido ati eyo kan (201), igba eyo atare o le kan (201), ao se irogbo kan si igba ati eyo kan (201), obi ifin a se si igba ati eyo kan (201 ), obi ipa na igba ati eyo kan (201), ewe amunimuye, ewe obirikolo omole kan, iko ode meje, a wa jo gbogbo re po, a wafi te odu Ifá osa meji. Ofo :Mo ri airi, mo ko aiko, bia ba ri, bia Ba mon, aipe lokọ, ti a ba pe oko, enu ama yo ni, enu o le yọ emi, emi mo orukọ re, me ko, emi mo, emi ri,mo mo oruko baba won, olobo pete, olobo momo, olobo momo gbomo mi toritori, tule omo on ni yi, tule omo emo ni, opa yinkin yin lobo, ni baba aje, ido ti e fi da ile aiye loro niyi, dakun mama fi da dede mi o, a fi sin gbere kokan si oju, asi tun sin gbogbo orikerike gbogbo ara, asi ma fi iyoku fo eko tutu mu.

4. A o gba gbogbo iye adie opipi, ewe abirikolo, erupe ipape ati aso ipade, ewe-ojiji, ewe-amunimuye, Ewe iyan, ao jo gbogbo re po, a o po mon ọsẹ ẹni na yio ma fi ose yi bo oju nigba gbogbo, beni ko ni ririkuri mon