OGUN SIMUSIMU

SIMUSIMU:Eniti amodi yi ba nse ni ojo to ti pe ni arun simusimu yi ma se, nigbati o ba ya ti arun na ti wo ni ara, gbogbo owo re ati ese re ni yio tutu rinrin, nigbana ni yio wa bere si lati ma simu piki piki, ohun ti a le lo niyi

1. Omi oja ikoko, ito malu, alubosa elewe, ewe taba tutu, ao se, ao ro sinu igo, eni na yio ma mu nigba gbogbo.

2. Epo igi ayan, epo igi amuje, epo igbo emi gbegiri, egbo orokoro, alubosa elewe, a o se ni agbo eni na yi o ma mu, yio si ma fi we nigba gbogbo.

3. Egbo apasa, ki se apasa ti imi esu o, ni ile odan ni agbe le ri egbo apasa o, epo igi ori, ile odan na nio wa o, alubosa elewe iti kan, ao se ni agbo yio jinna dada, wiwe ati mimu ni agbo nao.

4. Epo jebo, epo iroko, epo igi kuere, egbo-agbasa, egbo-aringo, ewe iyere lopolopo, ewe atare gbigbe lopolopo, ao se-ni agbo mimu ati wiwe nigba gbogbo, agbo yi dara pupo fun eniti o ru, ati eni ti iko ba mu ti o ba ngbe.