OKA AWONTANNA

OKA AWONTANNA Jẹ arun ti o buru ju. asi ma pa omo kekere ju lode-oni, nitori bi o ba mu omo gbogbo ara réni yio yo kasan laiseku si ibi kankan. Omo na yio gbe gbogbo ara re ko ni ju apa lo, bi o ba je wipe oka awontanna ni o mu omo na, ohun ti a si le lo niwonyi

1. Ewe ejinrin were, ewe alukerese, eru awonka, ao se awa ma fi ro omo na

2. Ewe alugbo okuta, ao su ni osuka mesan bio ba se okunrin, a si fi eru awonka kan si, bio ba se obirin (7) a si fi eru kan ‘si osuka ti a-su to je meje yi. a wa se ni agbo, mimu ati wiwe nio

3. Isu ogede wewe, epo kuere, eru awonka, ewe logbokiyan, ao se ni agbo, mimu ati wiwe ni agbo na o.

4. Ose, odidi alakan, ao sun eso ogoro, nigbati a ba sun tan, a wa jo alakan, oyun popojia, a fi obe re si mesan nibe, awa gun mo ose, ao fi ose yi we omo na nigbagbogbo.

5. Ongo isu, idoti inu apola ewure, ewe ilasa, ose, ao gun gbogbo re po, a ma fi we omo na.

6. Ewe ilasa, owo eyo mewa, etan eyin mewa, eru awola, ao gun gbogbo re po, a wa po mo ose awa ma fi we omo na nigbagbogbo

7. Eru awola, oko-ofe, egbo peregun, egungun agbari eja, eso oyo, ao gun gbogbo re po awa popo mo ọṣẹ,a wa ma fi we omo na nigbakugba.

8. Ewe agemo ogun, ewe abẹ alaran, ewe-awusako, Ewe dagunro, ewe-logunsese a o wa se ni agbo lori ina, ao mafiro omo na yio si ma fi we pelu.

9. Oga kan, asin kan, egbo ifon, epo Ogano, alubosa elewe, adi, ase niagbo, mimu ati wiwe.