OGUN ODE ORI

OGUN ODE ORI : Arun yi ni agbara pupo ju, a ma pa enia ki si tete pa-enia werewere, yio ko fi oju enia gbo ile dada, nigbati o ba nfo ni ori gbogbo ori oluware ni yio ma si pikipiki, awon ogun wonyi si kapa ode ori o.

1. Imi adie, etu ibon, egbo ekuya, egbo orombo were, kanhun bilala yinkinni, ata pupa, asa juku, egbo-ipeta, a o lo gbogbo re po, yio kunna dada, a wa fi omi orombo wewe si, a wa fi sin gbere lori, Igba si ni gbere na (200).

2. Ogbe ori akuko adie, eso ogbe ori akuko (21), asinpe ni agogo igun o, a walo gbogbo re po, a fi sin igba gbere lori.

3. Awon oju egungun, ao ja ewe ilasa merindinlogun, ewe isepe agbe merindiniogun, etutu eran esin tio ba ya aketan merindinlogun, ao ko gbogbore sinu awon egun yi, a wa fi sinu agbada ao jo gbogbore awa po po mo ose, yio ma fi fo ori na.

4. Etu ibon. oko atare kan, ao lo gbogbo re po yio kunna, a fi sin gbere ni ata, Igba ati eyo kan ni (201).

5. Igi aka tutu ao sa, yio gbe, a walo yio kunna lubulubu bi tire, a wama fin bi eniti nfin asa si imu nigbagbogbo

6. Egbo ekuya, ori elulu, ori oka, ori aparo, asa juku, kannafuru, ao lo yio kunna gege bi tiro, eniti ode ori mu na yio ma fin gegebi eniti o-nfin asa nigbagbogbo.

7. Egbo ekuya, egbo wowo, asa juku, eru awola, a gun gbogbo re mo ose, ama fi fo ori na sinu Igba eru, ama lo da si ori akitan.

8. Ojuoro, kanfo, ao ni jo kanfo o, erupe akitan, ori igun, iye aparo, ori agbe, odidi atare marun, ao jo gbogbo re po, awa po po mo ose ati kanfo, omi gbigbona ni a si ma fi we ori na.

9. Asa juku, asin, oga, ati epo atare, egbo yanrin, eru awola, omunu ewe iroko, ao lo gbogbo re po, 20 po po mo gse, oluware yio ma fi ose yi we ori na.

10. Ao lo egun ori aja, ao lo taba ogbugbu, ewe ina funfun, eru awola, a gun gbogbo re mo ose wiwe, ori na.

11. Igi taba, opolope eru awola, ogidi emu ni a fi se ni agbo, enina yio ma fi fo ori na nigbagbogbo.

12. Epa imi enia, ori ejo ti won ba pa lojo, ao jo ni ojo na, ori alabahun, ao jo gbogbo re nigbati o ba tutu tan, ao lo etu mo, a wa fisin gbere yi ori na po, awa tun fila lati iwaju de ipako, ode ori na yio si kuro nibe ni agbara Oluwa