OGUN OLONU

OGUN OLONU

OLONU Je arun ti on saba ma mu omode, asi ma wu omo ni iko, nigbati omo na ba nwu iko, ti e ba fi iye si, e ri nkan na ti yio ma yi ni egbe omo na. Ohun tia si le lo niwonyi

1. Epo pandoro, alubosa elewe, bio ba se obinrin, okuta ako 7, bi o ba se okunrin ni okuta ako 9, ao se ni agbo, ani je ki ina o ma ku ni idi re, oluware yio ma mu.

2. Agba meta (3), orogbo meta (3), a wa fi agba tele, awa ja ewe alukerese ati ewe ewuro odan, alubosa elewe, awa se gbogbo re po, agba ni yid tele o, mimu ati wiwe

3. Ewe-afee, ewe ejinrin wewe, eru awonka, a o se yi o jinna dada, odi wiwe ati mimu.

4. Egbolakosin, egbo gbogbonse, egbo-arunjeran, ita kun ito, ao se gbogbo re po, oluware yio ma mu yio si ma fi we nigbagbogbo.

5. Ewe efinrin wẹwẹ ati efinrin odan, ewe-sunyan die, egbo feru, egbo igi ita, ao se gbogbo re po, eni na yio ma mu yio si ma fi we.

6. Egho ipeta, egbo ifon, ewe-ajo, egbo enu opiri, inabiri, eru awonka, agun gbogbo re po, a wa po mo ose eni na yio ma fi we nigbagbogbo.

7. Roro odan die, jankawo die, odidi atare kan, ao lo mo ewe efinrin aja, a wa lo gbogbo re po, a wa fi sin gbere si egbe, awa fi ra.

8. Ikun ojia, ẹtu ìbọn, epa ikun, Egbo popojia, a o lo gbogbo re po, afi sin gbere kokan si egbe na.

9. Egbo akoko, egbo-oja Ikoko, agba kan, egbo akiti, a wa se ni agbo, oluware yio ma mu, yio si ma fi we.