OGUN OWOENU

OWO ENU je ohun ti kije eniti o ba mu o je ounje bi o ba se omo kekere ni o mu, ko ni le mumu dada, bi o ba si se agbalagba ni ko nile je ata, oto ni owo enu, oto si ni gbofungbofun.

1. Owo eyo kan ao lo, alomu die, akufo tanganran die, a wa lo, a wada sinu ketepe ogi, a wa wa iyẹ a wa ma fiyo enu omo na.

2. Ao sun egbo iyere ni ina, a wa lo alomu die si, a wa gbo ewe owe ahun, a wa da ogun ti alo yi si, a wa ma fi yo enu omo na.

3. Alomu, oje-akọmu, ao lo alomu, awa da sinu oje akomu, a wa fi owu ma ko omo nani ahan.

4. Akufo tanganran, kanhun die, kafuradie, ao lo, ama fi ra ahan na.

5. Oje lapalapa, a be ogede a fun omi re na, fifira ahan.