OGUN ORI FIFO ATI ORI TULU

ORIFIFO a ma fa Opolopo aisan wa, Iba a ma fo ni ni ori, Igbo naa a si ma fo ni ni ori pelu, beni oto ni ori tulu, oto si ni Ode ori, Ohun ti a si fe fisibe yi ko si arun ori fifo ti ko ba mu, sugbon Ogun yi ko ba ode ori mu, ohun ti a si le fi sibe ni yio

1. Ewe elu, ewe akuya, ewe ewuro, eru alamo, ao gun ni ose, a ma fi-kanhinkanhin tutu fo ori na sinu opon, amalodastakitan

2. Ewe elu, ewe ekuya, ewe emina, ewe ewuro, ewe aidan, ewe taba tutu, ao gun mo ose, ao mafi we ori naa si inu opon. a malo da si akitan

3. Ori aparo, erupe akitan, odidi atare kan, ao jo, a wa fi sin ori na ni atari ati iwaju, gbere na ko ni ye o.

4. Ewe-ekuya, Omunu ewe-Iroko, eru awola, ewe juku, ewe Isepe agbe, ewe egele, ewe orungo, a o fi gun ose, ama fi kanhinkanhin fo ori na, tutu ni kan-hinkanhin na o, ao ma da si orita meta.

5. Akuro alantakun mesan, eyo atare mesan, omu aro meteta ao bu diedie nibe, a o wa lo po, a wa fi sin gbere si iwaju, gbere na ko ni iye o.

6. Ewe efinrin aja, oko atare kan, ati etu ibon, a o lọ gbogbo re pọ, a fi sin gbere lori niwaju, gbere na ko ni iye o

7. Ikun ojia, ọkọ atare kan, koronfo eyin adie, etu ibon, ao lo po, ao fi sin gbere ni ori na.

8. Oju oro, egbo Akoko, epo iroko, ose die, osun die, efun die, a wa se ni agbo, nigbati o ba jinna, a wa wa ejinrin tia fi ma gbo ori na, nigbati o ba di ale ni a wa lo si ibiti o ba jinna dada, ori na yio si fun oluware ni alafia.