OGUN OKE ILE

Oke-ile je arun ti o buru, ama mu eke omode wu asi ma wu agbalagba na leke, oke-ile ko po mo nisinsinyi bi jinfun, iru eniti arun jinfun ba mu, bi é ba fowo te oluware lara, ogangan ibe ko ni dide, ohun ti si fa okeé-ile fun emode ni wipe opolopo omode lo ma nbu ogiri tabi ile je. Ohun ti a si le lo niwonyi

1. Egbo ipeta. baka, etu ibon, alubosa elewe, ipepe agbede, ati idaolerun. a ko sun idaolerun yi ni ina, a wa lo yio kunna, a wa gun mo baka, ipeta, etu, kanhun bilala, yio ma fi mu eko gbigbona.

2. idaolerun, a o sun ni ina, awa lo yio kunna, awa ko sinu awo, a wa fun omi orombo si, oluware yio ma fi mu eko gbigbona.

3. lyere, orogbo mewa, atare mewa, imi orun, idao agbede ati idao ilerun, kanhun bilala, a gun gbogbo re po a ma fi mu eko gbigbona.

4. Epa imi aja, imi elede, egbo ipeta, egbo ifon, adi, etu ibon, alubosa elewe, a wa se ni ipara, oluware yio ma fi para nigbagbogbo, yio si ma fi mu eko gbigbona.

5. Eresile ewe odan, eresile ewe lapalapa, okuta ako mesan bi o ba se okunrin, okuta ako meje bi o ba se obinrin, idao ilerun mesan bi o ba se okunrin, a wa pa pepe, a wa da sinu agbo na, a wade ni enu, bio ba se okunrin ni ojo kesan ni ato si, bio ba se obinrin ni ojo keje ni ao si, mimu ati wiwe fun omode ati agbalagba.

6. Egbo lapalapa, Irawe igbo, Irawe odan, ewe awusako, ase ale, ase aro, epo igi iyeye, ase ale ase aro Afa, alubosa elewe, omi iru ni a fi se, ao ma mu, a o si ma fi agbo na we nigba tia ba setan.

7. Egbo-gbogbori lopolope, isu ogede odo lọpọlọpọ, eru awola, omi Kanga la fi se omi re, ao sin oWo ero mesan ati eru mesan mo ikoko re, owu dudu ni ao fi sin o, oluware yio ma mu yio Si ma fi we ni igbagbogbo were ni ara oluware yio bo wa si po re.