AGUNMU INARUN

AGUNMU INARUN

OGUN NARUN:Narun je arun tio buru ju ti osi ntete so enia di Ogbo, a si ma ko ba awon okunrin pupo ju nitori wipe bi o ba poju ni ara enia ki jeki oko ole, beni ama fo enia ni oju, ohun ti a si le lo fun ni awon agunmu wonyi:

1. Egbo-gbogbonse, egbo-ipeta, egbo ifon, egbo agbasa, egbo-legunsoko, egbo tude, egbo inabiri, epo konunkoho, epo igi opele, baka, alubosa elewe, isu alubosa, ata were pupa, imi ojo dudu, atare 16, kanhun, ifofo okun, iyere, jankawo, eru awola, aidan ti o ba ni isu dada, a wa gun gbogbo re po, a ma fi mu eko gbigbona.

2. Ifofo okun, egbo akika, egbo isepe agbe, egboasunhan, baka, alubosa elewe, isigun, atare 10, orogbo 10, aidan, afara oyin igan, jankawo, imi orun, iyere, a wa gun gbogbo re po, eko gbigbona ni.

3. Egbo efo, eru awola, ata pupa, kanhun bilala, alubosa elewe, iyere, aidan, sasangbaku, a o gun gbogbo re po, eko gbigbona ni araro.

4 Asin mesan, Oga mesan, eru awola, isigun, gbogbonse, eru iju, ipeta, egbo ifon, alubosa, iru lọpọlọpọ, iyo, ata were pupa, baka, aidan, egbo agbasa, isu gbegbe ti o ba tobi, orogbo mesan, atare mesan, iyere, ifofo‘okun, egbo tude, egbo-ojolagbo, jankawo, afara oyin igan, kanhun bilala, etu ibon lọpọlọpọ, a gun gbogbo re po, ama fi mu eko gbigbona.

5. Egbo asunhan, egbo orombo were, iyere, isigun, ewe asunhan, egbo-atori, ati ewe atori, tangiri pupo isu aidan pupo, baka, alubosa elewe, kanhun bilala, ata pupa,iyo, lyere, a wa gun gbogbo re po, ama fi mu eko gbigbona.

6. Isu erin lọpọlọpọ, kannafuru lọpọlọpọ, egbo asunhan lọpọlọpọ, isigun die, egbo inabiri, egbo ipeta, egba ifon, ifofo okun, kanhun bilala, ata were pupa, a gun gbogbo re po pelu iyo, a ma fi mu eko gbigbona.

7. Epo ayin lopolopo, baka, egbo-agbasa, egbo aringo, egbo osunsun, obi ajopa 10, orogbo 10, koronfo eyin adie, kanhun bilala, ifofo okun, ata were pupa, ao gun gbopbo re po ati iyo, a ma fi mu eko gbigbona.

8. OSE:Ewe taba, eru awola, imi orun, ota inu iroko, ati okuta ako, ao gun gbogbo re po mo ose,a wa ma fi ose na we nigbagbo.

9. Ewe Agbasaboje, egbo akiti-tutu, epo ira tutu, ewe taba tutu, etu ibon, alubosa elewe, awa gun gbogbo re po mo ose, eni na yio ma fi we.

10. Egbo-ipapo, egbo ifon, egbo ipeta, egbo tude, -alubosa elewe, etu ibon die, egbo ope, egbo ako ibepe, eru awola, a wa gun gbogbo re po, ao wa ma fi we, ko ko enikankan o

11. Ewe-egburu, eru-awola, kanfo, somiroro, imi orun, alubosa elewe, egbo oruwo, a gun mo ose, oluware yio ma fi ose yi we nigbagbogbo, eni na yio si ma wipe ose gidigidi ni ose yi ise.

12. Egbo-seyo, egbo-orungo ati ewe re, ewe-ilasa omode, eru awola, eri ara oro tia je, egbo agba, egho-ipeta, etu ibon, ifon, agun gbogbo re po mo ose, oluware yio ma-fi ose na we.

13. OBE:Odidi adie kan, egbo-sajere, egbo ogbo die, isigun, baka, egusi, ao lo gbogbo re po, a fi se adie yi, ko ko fun enikenio, pelu epo, iyo.

14. Igbin, eja-aro, egbo-ipeta, egbo ifon, egbo-tude, baka, obuotoyo, ao lo gbogbo re po, a wa fi se igbin ati eja yi je, pelu epo, iyo.

15. Egba-kojomodiro, . egbo ologunsese, egbo arunjeran, egbo ewuro, alubosa elewe, iru, ata were, epo, iyọ, a wa lo gbogbo re po, a wa fi se obe alabahun Je were ni narun na yio fun yin ni alafia

16. AGBO:Egbo-sapo, eru tapa, baka, alubosa enisu, epa ikun, egbo-ira igbo, egbo agbasa, omi orombo were, omi orombo lakuegbe, egbo-ewon agogo, inabiri, tude, iti alubosa elewe, epo-oro, egbo ipeta, egbo-legunsoko, epo ira odan ati egbo re, tangiri, oro agogo, ati ọrọ adete, egbo enu opiri, egbo lapalapa pupa, omi aro, aroda awon miran si npe ni areda aro, a wa ko gbogbo re sinu ikoko nla, agbo tutu ni, ojo kesan ni ato si, wiwe ati mimu, narun na yio si fi oluware sile.

17. Epo pandoro, bia ba nto epo yi sinu ikoko ko gbodo siju soke, ewe finrin aja, efinrin odan, alubosa elewe, epo ogano, ao se gbogbo re po mo eru awola lopo-lopo, eniti narun ba mu yi yio ma mu yio si ma fi we.

18. Egbo-kakansela, egbo-ope, egbo arunjeran, egbo agbasa, egbo akara ajẹ, won si npe ni gboyingboyin, epo pandoro. egbo elu, egbo gbogbori, egbo ajalugbo- ogan, alubosa elewe iti kan, a wase gbogbo egbo ati ewe wonyi po, wiwe ati mimu ni agbo yi wa fun, o si dara pupo fun narun.

19. Ere sile ewe ako ibepe, ewe ija oke, ewe-ijan, egbo-ekanna awodi, egbo oruwo, eru awola ati egbo eru tapa, aidan, odi ope kekere ni ao fitele re, a wa se gbogbo re po, wiwe ati mimu ni agbo na