Ogun eti

OGUN ETI

Orisirisi arun ni o wa, awon arun ti ki fun enia ni alafia tio si je arun itiju, awon arun na ni wonyi: Eti didun, kokoro ela, ati wipe kokoro miran si tun wa ninu eti pelu, ohun tia si le lo fun iru arun bee niwonyi

1. Olu kan ti nhu ni ara igi tia npe ni ẹti igi, ao jo ati odidi atare kan, a o fi sinu adi, asi ma kan sinu eti na.

2. Olubongaga ati iye aparo, ao fi iye aparo ran fitila, nigbati o ba jo, a wa lo po mo olubongaga, a wa fi sinu adi, a wa ma kan sinu eti na

3. Epo betiro, a kan sinu eti na, ina ko si gbọdọ debe.

4. Ewe-egele, odidi aparo tiyetiye re, odidi eiyele tiyetiye rẹ, odidi ẹlulu tiyẹtiyẹ rẹ, epa imi gbigbẹ, ao ko sinu konjo nla kan, adieyan, adi yio dun dada ti yio po, bi o ba se omode, a ma fi adi yi ka leti ni, bi o ba se agba, ao ma kan sinu eti na.