Ogun Egbo

OGUN EGBO

1. Ikun-ojia, sunadare, efunlẹ die, okan owo eyo, aolo gbogbo re po, awa fun omi orombo were sí

ao gbo ewe lapalapa, omire ni ama fi we ese na ki a to fi ogun ti a lo yi si.

2. Iru, kanun die. Iyo die, ọsẹ, ao gun gbogbo re pọ mọn ara won, ama fi we oju egbo na

3. Epo oṣe ao sun ni ina, a wa lo ti yio kunna dada, ama ku le oju egbo naa, werewere ni egbo na yio san.

4. Egbo-ẹlu, a sun,a wa lo ti yio kunna gidigidi, la wa ma ku le oju ese na, were ni yio pa kokoro oju ese na.

5. Olodun tabi jube: Egbo ata, egbo ewuro, agbo ipeta, egbo sajere, oronro malu, adi, ori, epo, omi orombo lakuegbe, omi orombo were, ati ata were, ao lọ die si, a wa se gbogbo re po, yio jinna dada. iba se egbo, iba se lobutu ti o tu, a ma bu le loju nigbati a ba we tan, were ni oluware yio ni alafia.

6. Eso ori, ao sun pankara, ao da sinu adi,a ma bule oju egbo na nigbati a ba we tan.