OGUN DAGBE

OGUN DAGBE

Opelopo arun ni o nfa ki enia ki o ma ya igbe, elomiran nipa jije ohun ti inu re ko gba. Ohun ti a le lo fun iru arun be ni wonyi

1. Eha igba ti awon oni hagbahagba ma nha, aolo lubulubu, a o fi odidi atare kan kun, eko tun nia ma fifo mu.

2. Ajesi adie, aolo pelu odidi atare kan, ama fifo eko tutu mu.

3. Ewe damida ebi, ketepe ogi, odidi atare kan ao jo gbogbo re po ao ro sinu ato, a otu ato na ni enu ati idi, bi enia ba nbi, a oti idi bu, bi enia ba nsu ati enu bu, eyiti a ba bu nibe, ao te ni ejiogbe.

Ofo re: A ki ti enu su, a ki ti idi bi, a fifo eko tutu mu.

4. A gbe koto lọọdẹ, a wa bu omisi yio kun dada asi ta epo die si, ati jankawo die, o dara pupo fun dami da ebi, e bu siinu igba, ao mu.

5. Irinkolo, a sun ni ina, nigbati o ba pon, a wa lo lori okuta ti yio kunna dada, fifo eko tutu mu.

6. Agbarin, etu ibon ao jo agbarin, la wa lo mo etu, ama fifo eko tutu mu, o si dara fun igbe orin

7. Eso la pupa, ao jo, a fi etu ibon die si, nigbati o ba tutu, ama fi fo eko tutu mu.

8. Epo awusa, akasu eko, odidi atare kan, nigbati a ba jo tan, ati eko, awa lo ikun ojia si, ama fi fo eko tutu mu

9. Ewe Imiesu ati ewe ogbo, ao gbo mejeji po, a o ma mu, Igbe na yio si da.

10. Ewe ẹlu kowe, ewe atori, ao gbo awon ewe mejeji po mo ara won a si mu

11. Efun-ado, ao lo yio kunna dada, pelu tiro, ao ma fifo eko tutu mu nigbagbogbo.

12. Erupe amo ti won fimo ikoko, ati lẹu ope, a o lo yio kunna, ao ma fifo eko tutu mu

13. Ewe-agbado tutu, omunu arunjeran, ao gbo, a Si mu igbe na yio si da. .

14 Eso boni, ao gun, alubosa elewe, a o gun, a wa ro sinu igo, awa ma mu nigbati ongbe ba ngbe eniti nyagbe na. Osi dara fun-igbe orin papa. |