OGUN EJONU PELEBE

1. Egbo ikanyanrin, egbo ifọn, ikun ojia, egbo etiponnola, iru, alubosa, ata, iyo, aolo yio kunna, a wa su rodorodo yio ma fi mu eko gbigbona.

2. Egbo orombo were, Egbo orombo Lakuegbe, egbo isinko, isinko odan ni ki se isinko igbo o, egbo ko jemoduro, egbo dasa, a wa bo epo gbogbo awon wonyi, a wa gun gbogbo re po, ogiri, iyo, kanhun bilala, Iyere, a si fi awon nkan merin yi kun pelu, ama fi mu eko eko gbigbona.

3. Epo igi abado, adi, ao se ni agbo oluware yio ma mu, gbogbo ohun ti nje ejonu pelebe yi ni oluware yio si su, lai ni seku ni ara re.

4. Ododo igba ta fi se iru, aojo, a lo etu ibon die, ati tiro si, yio ma fifo eko tutu mu.

5. Eso ẹgẹlẹ yio po, tiro, kanhun bilala, a wa lọ gbogbo re ama fi fo eko gbigbona mu.

6. Eso lapalapa yio po, oyin igan, kanhun sinsin, ao lo gbogbo re po ama fifo eko tutu mu.

7. Oje ẹnu opiri, adi, a kan si eko tutu a fo mu, o si dara fun jedijedi wẹrẹ.

8. Egbo igi iru aya, egbo lakosin, isigun, iyere, baka, alubosa elewe, a wa gbogbo re po, adi, ori, epo, ẹran ẹtu la fi se je.

9. Omunu asunhan, ewe ehin olobe, a o lo yio kunna, a fi se odidi abo adie, epo, ori, adi, iyere, ni ata re, iyọ, a wa se yio jinna dada, kato ma je, enu ko gba irohin ni ogun yi, eniti o ba lo ogun na lo le mo gege bio ti rí.

10. Egbo enu-opiri, egbo inabiri, egbo isigun, alubosa, iru, ewe patanmo, a o lo yio kunna dada, eran ewure la fi se Je