Ogun Afose

OGUN AFOSE

1. Egbo Omisinmisin gogoro, Itu, Ata were, Iyo, Ewe ọlọyinyin, ao lo gbogbo re po, a wa ko sinu Iwo ewure, ti a ba ti ko sinu iwo na tan ao wa fi kan enu a wa pe

Ofo re: Ata ki kohun obe, Iru ki ko ohun obe, Iyo kiko ohun obẹ, Ewe omo loyinrin ki pa ohun oba orisa da, o da fun tia ba fe lo ose awure, o si tun dara fun adura gbigba bakanna.

2. Ao ke irogbo si igba (200). Ao wa eyo atare Igba (200), obi ifin igba (200), obi ipa gba (200), a wa da apo aso kijipa funfun tia npe ni Fu. A o wa egbo amureju, a o fi se orin, awon obi ipa, ati ifin wonyi ao ke awon na si ona igba ni o (200), a o ma Je atare wonyi mo orogbo ati obi, ao marun orin yi ao sí ma sure si, tabi ka ma fi se adura, ao wa ma fi gbogbo re pamo si inu aso yi, (aso Fu), kijipa funfun ti a da ni apo.

3 Ilako kan, Abẹrẹ kan, Abẹrẹ baba kan, Abere Oje kan, Ao wa fi Obuotoyo si oju ilako, A wa lo ewe oloyin a wa fi si, a o wa ko si oju Igbin pelu ewe oloyin na, ao si re fun ojo meje, ti o ba ti ko kuro nibe, ema fi banutie bafe soro si enia. O si tun dara ti enia ba fi soro si ogun, ogun na yio si Jẹ ni oo.