Norctunal Seizures (Ogun oru)

OGUN ORU Je arun ti o buru ju, beni kisi se wapa, ki si se won ni osan, a fi oru nisaba ma se won ti yio si ma pariwo nigbati o ba de si oluware. Awon ogun wonyi si kapa re gidigidi,

1. Odidi igun kan, eso apa, eso afon, odidi apola aja, a o jo gbogbo re po, nigbati aba jo tan, a wa se obe gbegiri, igbin, omi orombo nla, a wa fi se obe, a wa da gbogbo ohun tia jo yi si, adi, ori, epo, obuotoyo, ko ni iyo, nigbati o ba je tan, yio wa lo fo isasun sinu igbe

2. Egbo woruku, ewe-sawerepepe lopolopo, apola aja, apola okete, ati ifun ati edo ohun ti mbe ninu pepeye, odidi elegede kan, a wa be kekeke, a Wa ko sinu oru, adi, ori, epo, a wa da sinu oru, a wa di ni enu, ni ojo kesan nia to sio, oluware yio wa ma to la dada, tabi ki oma da sinu eko gbigbona ki o ma mu.

3. Apola aja, ao kan oje ọrọ si, a wa yan yio gbe dada, odidi igun kan, eso apa, kerewu, eru awola, ao Jo po mo apola ajayi, atun wa kan oje ọrọ Si, nigbati a ba jo tan ni o, ninu adi ni yio ma fi si nigbati oba fe la, oluware yio ma lo nighagbogbo ni o.

4. Alangba merindinlogun, omole merindinlogun, ajepo adan, epo aja, a ko gbogbo rẹ sinu oru, egbo woruku, ewe-sawerepepe, ewe dasaa, ewe orira, a wa ko le ori ti akoko ti a ko sinu oru, adi, ori, ewe gboro, a wa ko le, a wa san ni ibo, ni ojo kerindinlogun ni a to si, yio ma tola, yio si ma fi mu eko gbigbona, were ni yio si san, ni Ogo Oluwa.

5. Apola elede. imi oluware yio ko sinu oru, ifun adan, ifun oka, ogoji adigbonnanku, ekolo ologi lopolopo, ewe sawerepepe, egbo-woruku, ao ko sinu oru adi, ori, epo, obuotoyo, oluware yio ma la, yio si ma mu kii se sise o.

7. Apola okete, bi o ba se obirin abo alangba mesan, bi o ba se okunrin ako alangba mesan, odidi awo lili a o jo, odidi ito kan ao jo, eso apa lilo ni a lo ki se jijo, a wa jo gbogbo re po, nigbati aba parire tan, omi oja ikoko ati etu ibon, a silo sunadare die si, adi, obuotoyo, a wa da gbogbo re po, eni na yio ma mu Nigbagbogbo.

8. ASE PA tabi APAGBE Ao se gbegiri yio k!, a de di,ojo keje, akara meje, a ju sinu gbegiri yi di ojo keje, akara kengbe ni o, a wa ra odidi kannakanna kan ati odidi igun kan, a wa jo mejeji po, ni ojo keje tia ba gbe gbegiri yi jade, a wa gbe ka ori ina, a wa se ti on ti akara ti a da si titi ti yio fi jona, bi’ jijo,a wa da eyiti a ko jo si, a wa toju igbin, a wa toju isasun tuntun, adi lopolopo, ogun ti a jo yi ati adi, a wa fi se obe igbin, a wa fi iyerosun te gbogbo ifa odu merindinlogun.

Ofo:Awonayin wonyin takoro, awonyin wonyin takoro, okoko moka, Akingbowo, Akingbese, ma gbewo lagbaja mo, ma gbese re mo Akingbowo lape iku, Akingbese lape arun, Awonyin wonyin takoro loruko tia pe ogunoru, oluware yio ma je obe na.

9 Adie opipi, aparo kan, apola aja, ao jo awon me teta po, adi, ori, a fi se eran elede je. A jo ekolo ologi ati alangba meta ati omole meta, a jo po mo metata ti akoko, awa fi gbogbo re se obe na. Oluware yio ma je.

10. Omi ogede odo lopolopo, ose die, opolo meta, epo igi abado tutu ti a ba pa lojo, omi oja-ikoko, ao se gbogbo re po yio ma mu ni idaji, were ni yio si po arun na sile.