OGUN OJU DIDUN

Oju didun je ohun pataki fun gbogbo éda, a si ma fa ilo Si ehin fun awon Opolopo enia, ohun ti si fa oju didun na ni wonyi

Igbona sanponna a ma fa ti elomiran, Narun asi ma fa ti elomiran, Nina Owo sini loju a si ma fa ti elomiran, Ohun ti a si le lo fun won niwonyi.

1. Kafura, kannafuru, epo ogano die, oju oga mejeji, oju eiyele mejeji, tiro, akufo tannganran, a o lo, oluware yio ma le si oju na.

2. Ibo oju Igbin, kafura, kannafuru, akufo tanganran, oju eiye elulu mejeji, oju iki mejeji, oju aja Mejeji, oju eja ojiji mejeji, a o lo gbogbo re po mo tiro, a wa ma fi le oju na, sugbon bi a ba se ogun yi si ọwọ ogun enia le lo, tabi’ju be lo.

3. Epo-ogano die, akufo tannganran, oju ejo kejo mejeeji, oju omole Mejeji, oju oga mejeji, oju elulu mejeji, oju adan mejeji, alomu die, kafura die, kannafuru die, ao pa eso lapalapa, awa yo egusi inu re, a wa lo mo gbogbo re, awa po mo firo, oluware yio ma fi le oju na.

4. Omi inu agbon, eso lapalapa, kafura, kannafuru. a o lo gbogbo re po, a wa ro sinu igo, a wa fi omi agbon yi se omi re, a wa ma fi iye eiyele kan omi re si oju na

5. Omi igbin. kafura die, omi agbon, a o ro sinu igo, wa ma fi i iye eiyele kan si oju na nigbagbogbo.

6. A o mu igo lo si idi igi opoto tabi awo tannganran, a o gbẹ ilẹ jin, a wa ge egbo igi na, a wa fi igo tabi awo ta mu lọ yi gbe omi ti egbo tia ge yi-ba nsun, a gbe ti yi o to bi igo meji, a o lo kafura si a wa ma fi iye lekeleke kan si oju naa

7. Oju alangba mejeji ati imi re, oju oga mejeji, Egbo Gberefutu, awon oju egun, oju pepeiye mejeji, akufo tanganran, oronro oka, kannafuru, kafura, a o lo po mo tiro, awon oju egun yi nia fi ma fitiro na pamo si ninu

8. Omi agbon, eso lapalapa, owo eyo, ao fo yio fun fun, omi odo kanga, a fi omi odo kanga gbo ewe ido, awa fi ajo gba omire, ao da ewe re nu, a wa fi owo eyo yi tele sinu tanganran olomori, a wa da omi ewe ti agbo yi le, a wa ma la oju si inu ogun yi ni igba meta lojojumo.

9. Isu wowo, kanfo, kafura, kannafuru, a wa gun mọn ose, a wa ko ọṣẹ yi sinu aso funfun, a ma fi ose yi we oju na,

10. Omi agbon, omi igbin, ewe jogbo, ao fi omi igbin ati omi agbon gbo ewe jogbo, a wa fi ajo gbe omi ewe ti agbo yi, a wa ma fi iye lekeleke kan si oju na.

11. Ewe-tude, aora lọwọ, ao fun omi ewe yi si oju na.

12. Ibo-oju-igbin, koronfo eyin eiyele, koronfo eyin adie, koronfo eyin eiye ega, ọhọ alangba, oho oga, ao lo gbogbo re po mo tiro, obirin ti ko ba timo okunrin, tabi okunrin ti ko ba ti ba obirin sun ni yio ba ni le tiro na, a wa ma le si oju na, were ni yio si fuye.