Idi Pataki ti Oogun Tapa, Jẹdi Jẹdi ati Idi yiyọ ko fi ki n ṣiṣẹ lára ẹni ati ohun ti a le ṣe ti yi o fi sise
Opolopo ni o ti lo Oogun tapa tabi Oogun Jedi Jedi ati Ogun ìdí yiyọ ti awon Aisan náà ko sí lọ, ohun ti o si ma n fa naani Fi Fi oogun ori fifọ wo Inu rirun.
Iyatọ wa laarin Jẹ̀di jẹ̀dí ati Idi yiyo bi o tile je wipe awon Arun naa Fi Ara pẹ Ara won
Kini Iyato to wa laarin Jẹdi Jẹdi ati Idi Yiyo ni ipa ti oruko
Jẹdi Jẹdi ni a má n pe ni pile tabi haemorrhoid ni oyinbo, Idi yiyọ ni a n pe ni rectal prolapse.
Ni igbati ati Mon Iyato Nipa Oruko won yii, a o maa se Alaye ohun ti o n je jedi jedi ati Idi Yiyo ki a le baa Mon Iyato gedegede ti o n fa asilo oogun ti kii je ki awon Aisan naa o lo nigba ti won ba Fi orisirisi nkan wo won
Kini A n pe ni Jedi Jedi
Jedi Jedi je àisàn ara nigbati iṣan ti o wa ni ibi furo ba wu tabi o lẹ ti kò sí ní agbára mon, eleyi ma n saaba ṣẹlẹ ní igbati igbọnsẹ eniyan ba le koko yi o sì máa jẹ kí ẹnu odi o máa ran, eni naa yi o máa gbin tabi ranjú ti o ba fẹẹ se igbọnsẹ, eleyi a máa di eyin riro tabi gbogbo ara ni riro ni igbamiran. Jedi Jedi ni o ma n fa idi yiyọ ni opolopo igba bẹẹni a máa ṣe àkoba fun omokunrin lati see daadaa lodo abo.
Yatọ sí ti igbọnsẹ eni ba le ni aleju, jije ohun didun, bakan naa, omo bibi náà a maa fa ki eniyan máa rí àwọn àmì ti o jọ ti jedi jedi.
Kini a n pe ni Ìdí yiyọ
Ìdí yiyọ ni nigbati abọ idi eyi ti a tun má n pe ni Orobo idi (rectum) ba yo si ita. Eleyi le je nkan ti o da eru ba eniyan lopolopo sugbon kii see ohun to buru pupo, bi o tile je wipe bi aisan naa ba se n pe Lara to ni yi o SE maa di ohun nla ti yi o si maa lewu si
KINI AWON AMI AISAN ATI ISORO TI JEDI JEDI A MAA FA SINI LARA
1. Ki eje o maa wa ninu igbonse
2. Ki enu idi o maa ro eni
3. ki enu idi o maa yun eni
4. Ki a maa ranju se Igbonse nipase igbonse ti o le koko
5. ki a ma ri igbe ya rara
6. ki o maa se eni bii wipe igbonse si ku ti igbonse si ti tan
7. ki oko omokunrin o ma le daadaa
8. ki omokunrin o maa tete da omira
Ni opolopo igba kii se jedi jedi ni o man fa a i se deede okookunrin tabi ti okunrin ko ba le ni ibalopo daadaa eyi ti a mon si IDAKOLE, ohun miran ni o maa n fa, sugbon o maa n sele pelu jedi jedi naa ni igba miran ati ekookan ni igbati isan enu idi yii ba ti wu ti o si di eje sinu, a maa fa ki eje ti o n lo si ibi oko ki o maa to mon ti oko naa ko si nii le daadaa
Awon ohun ti o maa n fa Idi yiyo
èyí ma n sáábà ṣẹlẹ sí ẹni tí o ba ni Jedi jedi, tabi eni ti o ba sẹsẹ bi ọmọ tan lati ipase gbigbin, ri ran oju ya igbẹ tabi gbigbin ni asiko ibimo. Awọn miran ti idi won ma n yo naa ni awon ti won ba ti ni ìpalára ri ni ibi ikun wọn tàbí ìgbaròkó/Idaji ara won rí. Idi yiyo a máa ṣẹlẹ sí àwọn tí o ba ni Jedi Jedi ojo pipe lara nitori a máa nira fún wọn láti rí igbẹ ya tabi igbọnsẹ won ma le koko, ti wọn sì má n ran ju se igbọnsẹ, nipasẹ eyi Orobo/abo idi wọn yóò ti ri wahala ju, kò sí níí ní agbára mon eyi ti ti o mu lati maa ta jade sita tabi
Bi a se n toju Jedi Jedi
Ọhun tí o dara ju ni lati de ọnà Jẹdi Jẹdi ki a si ma ni, so maa so bawo ni a se n dènà Jedi jedi ki a too wa so iwosan re ti o ba sele wipe eniyan ni
Bi a se n dènà Jedi Jedi
1. Omi mímu lòòrè koore: eyi yi o máa jẹ kí ohun je wa ki o máa lọ (digest) dáradára ti igbọnsẹ wa yi o sì máa darí, ko nii sí wípé a n ran oju se igbọnsẹ mọn
2. Ki a máa tètè lo si ile igbọnsẹ ni kete ti igbọnsẹ ba ti n mu ni, ki a máa pa igbọnsẹ mọn ra a máa fà ki igbọnsẹ o maa le, kì a sì máa gbìn tabi se enu idi ni wahala kì a too ri igbọnsẹ se, eyi ti o le máa fa jedi jedi ati idi yiyọ
3. Ki a máa jẹ ounje ti o ni okun
Awọn ounje wo ni o ni okun ni ile Nigeria ati ni ilẹ Yoruba: Ounjẹ gẹgẹ bí Rice, Agbado, ẹ̀wà, spaghetti, fufu, carrot, apples, Ogede, Garri/Eba, fufu, Abacha, semo, Amala ati beebeelo
4. Ki a máa ṣe Eré ìdárayá, ki a má ṣe máa joko sí ojú kan náà ni gbogbo igba, eleyi ko dára fún ara yato Si fún Jedi Jedi nikan
BI A SE N TOJU JEDI JEDI PELU OOGUN
Tangiri, a o be eepo eyin re kuro, a o tun wo koro ati sukusuku inu re danu. a o ko iyo, a o be weere, , a o ro sinu igo, a o bu omi si , o di mimu
Bakan naa e le ra Sakora Pills nibiyi, o je oogun Jedi jedi oni horo ti a fi ewe ati egbo ibile se, Ajebiidan ni ti ko si elegbe re ni ile Nigeria
Bi a se n toju Ìdí yiyọ
Ni igba miran Idi yiyọ a máa lọ ti a ba ti toju Jedi jedi tan ti a si n Fi owo tii wole, A lee dena Idi yiyo pelu awon ona ti a n gbaa dena jedi Jedi sugbon ni igbamiran ko nii lo, a o sì nilo lati se itoju re loto ni
Oogun Idi Yiyo
Ewé Igi òrúru, Akogun, Àlùbósà Elewe, A ọ lọ gbogbo rẹ pò, a ọ máa fi muko gbigbona otàn
Ona miran ti Atun le Gba Toju Idi yiyo
Ẹrẹlẹ ewe ipin, padi atare kan, a ọ jọ pọ, a o po pọ mọn orii, a ọ ma fi pa ẹnu furo eni naa otàn
Fun ibeere tabi Alaye, e Kan Simi ni ibiyi
E jowo, kini geesi ewe igi òrùru, akogun
emi naa ko mon oruko oyinbo won, sugbon n o se iwadi, n o si fun yin lesi lai pe
kini a le lo si idi yiyo olojo pipe yato si Ewé Igi òrúru, Akogun, Àlùbósà Elewe, A ọ lọ gbogbo rẹ pò, a ọ máa fi muko gbigbona otàn
kini a le lo si idi yiyo olojo pipe yato si Ewé Igi òrúru, Akogun, Àlùbósà Elewe, A ọ lọ gbogbo rẹ pò, a ọ máa fi muko gbigbona otàn
E send message si mi ni whatsapp number pẹlu number yii 09023245320
E seun, mo ti mo iyato jedi jedi ati idi yiyo bayi