
Iwulo Ewe Ogbo ninu ara
Kíni a n pe ni ewe Ogbo
Orúkọ ewé yìí ni à ń pè ní Ewé Ọgbọ́ ní Ilẹ̀ Yorùbá, àwọn Òyìnbó asì máa pè é ní African Parquetina. Àwọn Haúsá a máa pè é ní kwankwanin, Ígbò a máa pè é ní Mgbidin Gbe, Àwọn Ìgbò ti Àsàbà a máa pè ní Otonta. Awọn Ígbò a máa fi Ewé Ọgbọ́ se ẹfọ̀ jẹ. Orúkọ tí awọn oni imọ ìjìnlè sáyẹ́ńsì fún Ewé Ọgbọ́ (botanical name) ni Parquetina nigrescens. Ewé Ọgbọ́ jẹ́ ewé tí ó wúlò púpọ̀ nínú ìsègùn ìbílẹ Yorùbá tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò sì mọn irú iṣẹ́ tí ó ń se
Ninu ìsègùn ibilẹ, a le lo Ewé Ọgbọ́ fún ẹni tí ẹ̀jẹ̀ rẹ kò bá tó, eni tí ó ní àrun Awọ ara tàbí tí ara rẹ kò bá jọ̀lọ̀ látàrí àwọn kòkòrò inú ẹ̀jẹ̀ kan tàbí òmíràn.
Atún le fi wo o àìsàn ara ṣíṣú tabí kòkòrò awọ ara èyíkéyìí. Èyí tí ó mú Ewé yìí jẹ́ ewé kan tí ó dára fún àwọn Àgbàlagbà lọ́pọ̀lọpọ̀ ni wípé ó dára fún Ìtọ̀ ṣúgà à sì máa dín àpọju ṣúgà ku ninu ara
Yàtọ̀ sí ohun ìlera, A tún ma ń lo Ewé Ọgbọ́ nípa ti ẹ̀mi ati aajo, a máa fi se Òògùn Ẹ̀yọ́nú, a máa fi se Awọ́rò, bẹ́ẹ̀ni a sì má ń fi se e òògùn ìfẹràn fún okùnrin àti Obìnrin
Níbo ni a ti le rí Ewé Ọgbọ
A leè rí Ewé Ọgbọ́ káàkiri gbogbo agbègbè ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ní ibikíbi tí a bá ti rí igbó kékeré, á o sáábà máa rí Ewe Ọgbọ́ nibẹ̀. Ewé Ọgbọ́ a màa fò mọ́n ara odi (fence) ilé, a máa fò mọ́n ara igi, Ewé Ọgbọ́ a máa fà bíi itakun
Bí a se n fí Ewé Ọgbọ́ wo Àìsàn ati àwọn Àìsàn tí a ń fií wò
Àwọn Àìsàn tí à ń fi ewé Ọgbọ́ wo ni ìwọ̀nyí:
1. Ìtọ̀ ṣúgà
2. Kòkòrò àti idọti inú ẹ́jẹ́
3. Fún ìpèsè ẹjẹ
4. Fún Ara tí kò jọ̀lọ̀
Bí A se ń tọ́jú Ìtọ̀ ṣúgà pẹlú Ewé Ọgbọ́ (Parquetina nigrescens)
Gbà òògùn tí ówà lára ewé yìí kúrò nípasẹ̀ Gbígbo o sínu omi, ewé yìí kìí tètè toró, nítorínàà o ni lati lo ewe pupọ lati gba ohun ti o to 25cl òògùn yìí tí o si ki, rii daju pe o ko fi omi púpọ po o. Omi kekere ti a fisi wa lati je ki ewe naa toro ni, nitorinaa ko nilo omi pupọ lati lu oogun naa. O le lo ẹrọ ti a fi n lo nkan (blender) lati je ki o rọrun, da Ewe Ogbo ti o to sinu blender , ṣafikun omi diẹ ki o le dapọ daradara, ti o ba kuna, wa ewe naa kúrò ki o ṣe ṣe pẹlu asẹ́, omi ti a se kuro nibe ni oogun naa ti o wulo, a o da awon ewe ti o wa nibe nu .
Lilọ rẹ: Mu Oṣuwọn 25 cl Òògùn yìí ní èèmeta laarin ọsẹ kan. Bi ito ṣúgà yìí bá pọ lara rẹ, yi o sì wá lẹ, bi sugar tí o wa ninu eje ba mọn ni iwonba bi onṣẹ yẹ ki o wa, òògùn yìí tí o tubo mu wa ni iwonba, ti ko nii kere ju tabi po ju
Bi a se n lo EWE ogbo fún kòkòrò inú eje ati eje ti ì bá dótí
Gbà òògùn tí ówà lára ewé yìí kúrò nípasẹ̀ Gbígbo o sínu omi, ewé yìí kìí tètè toró, nítorínàà o ni lati lo ewe pupọ lati gba ohun ti o to 25cl òògùn yìí tí o sì ki, rii daju pe o ko fi omi púpọ po o. Omi kekere ti a fisi wa lati je ki no toro ni, nitorinaa ko nilo omi pupọ lati lu oogun naa. O le lo ẹrọ ti a fi n lo nkan (blender) lati je ki o rọrun, da Ewe Ogbo ti o to sinu blender , ṣafikun omi diẹ ki o le dapọ daradara, ti o ba kuna, wa ewe naa kúrò ki o ṣe ṣe pẹlu asẹ́, omi ti a se kuro nibe ni oogun naa ti i wulo, a o da awon ewe ti o wa nibe nu.
Lilo rẹ: A o maa mú 25cl ni ẹẹmerin losẹ
Bi a se n lo Ewe Ogbo láti pèsè Ẹjẹ fún ara
Gbà òògùn tí ówà lára ewé yìí kúrò nípasẹ̀ Gbígbo o sínu omi, ewé yìí kìí tètè toró, nítorínàà o ni lati lo ewe pupọ lati gba ohun ti o to 25cl òògùn yìí tí o si ki, rii daju pe o ko fi omi púpọ po o. Omi kekere ti a fisi wa lati je ki no toro ni, nitorinaa ko nilo omi pupọ lati lu oogun naa. O le lo ẹrọ ti a fi n lo nkan (blender) lati je ki o rọrun, da Ewe Ogbo ti o to sinu blender , ṣafikun omi diẹ ki o le dapọ daradara, ti o ba kuna, wa ewe naa kúrò ki o ṣe ṣe pẹlu asẹ́, omi ti a se kuro nibe ni oogun naa ti i wulo, a o da awon ewe ti o wa nibe nu. A o fi miliiki si
Ti a ba n lo fún ẹni tí ẹjẹ rẹ kò to ní hospital ti o sì nilo ẹjẹ, láàrin iseju meedogun, eni náà yóò ní ẹjẹ yóò sì gbádùn
Bi a se n fí Ewe Ọgbọ́ wo kọkọrọ awọ ara
Egbo ọgbọ́ (Egbo idi re gangan Kiise ewe), Egbo Sagere, Ẹnu Òpiri, Alubosa Eléwé, a o ko gbogbo re sinu ikoko, a o rẹ pẹlu Omi tútù fún ọjọ meta, ti o ba di ọjọ kẹta, a o maa mú. Bakan naa, a leè ra Ọsẹ Zeezah fún gbọ kòkòrò ara eyikeyi
Fun eyikeyi ibeere yin, e lee ba mi soro ni ibi yii
Leave a Reply