OGUN JEDIJEDI

OGUN JEDIJEDI

Arun yi ki je ki omode ati agbalagba ori igbonse se, ama rin enia nidi ti o ba nse obirin ko ni je ki o tete loyun, ti a basi nlo ogun yi fun iru enia be yio ni alafia.

1. Ao mu ẹkọ lọ si ibiti enu opiri wa a o kan oje re si, ao fo mun ni owuro, fun agbalaghba ni eyi o.

2. Ao ko oje oro agogo, oyin-igan ati omi ireke, ao se yio jinna dada, agba yio mu sibi kan laro, o dara fun bi obirin ba nse alejo lowo.

3. Etu ibon, tiro, eso awogba arun, egbo aje o ba le, ao lo gbogbo re yio kunna dada, ao ma fi mu eko gbigbona. Odara fun obirin ti ba nse awari pupo, ati papa o dara fun obirin ti inu re ba ngbona, lasiko tio bari alejo.

4. Omunu asunwon, korofo eyin adiẹ, alomu die, kanhun bilala, a sa omunu asuwon yi ni ao wa lo ti yio kunna dada, ao busi enu, ao fi omi tutu gbe mu.

5. Omunu asunwon, ao fi pepe re, kanhun bilala, ao fi sinu ape, a wa fi ro oka je, Ni agogo mejila ni ao to jeun.

6. Tiro, eso osan, baka diẹ, ao lo yio kunna dada, ao fi ori si, ao ko sinu ikakara, ao ma fi bo omode nidi.

7. Ewe asaragba, omi orombo lakuregbe, alubosa elewe, nigbati a ba se agbo yi tan, ao wa lo kanhun die si, a o wa ro sinu igo, a ba bi omode loni, a ma nlo fun aboyun, ki se pe eyi nikan ni on je fun, a ma je fun gbogbo arun.

8. Epo-ayin, epo pandoro, epo laoro, ewe asunwon, ewe lakosin, alubosa elewe, agbo ni, o dara fun omode o dara fun agba

9. Ewe ajekobale, ewe asunwon ebo, kanhun, ao se ni agbo ni ao ma mu