BI ENIA BA NRU

BI ENIA BA NRU

Orisirisi arun ni ima mu enia ru

Iko egbe, Atosi, Ile Igbona, isi epolopo eje ni ara lo pa ri gbogbo rẹ.

1. Egbo eruju, egbo ifon, opolopo aidan, egbo lobotuje, alubosa lopolopo, ao wa se ni agbo tutu, a bere si fi we ni ojo 7, bi o ba se obirin, bi o ba se Okunrin, ni ọjọ kẹsan ni o. A sima mu.

2 Epo igi aya, epo igi ara, epo amuje, egbo seyo, egbo ako ibepe, ao se agbo, ao fi ẹru, awola ati alubosa elewe si, yio ma fi we, yio si ma mu

3. Epo igi aye, Epo igi iroko, epo igi sapo, epo igi kuere, epo igi ogano, epo igi ipeta, epo igi pandoro, a bu esan ekuro tele, okuta ako mesan bi o ba se okuorin, bi o ba se obirin 7, a wa se ni agbo yio ma mu, yio si ma fi we.

4. Egbo ọgbọ, igi taba, eru awola, ao se, yio jinna, yio wa ma fin biigba enia nfin turari, ki se mi mu o

5. Egbo elu, egbo peregun ati ewe re, isu idi ogede were, odidi odi eyin kekere kan, yanrin odo, agbo tutu, bio ba se okunrin (9), bi o ba si se obirin (6)

6. Egbo kanranjangban, a o lo iyere mo egbo yi, eran wure, epo, iyo, ata, a wa se yio jinna dada, alamodi na yio ma je.

7. Egbo tude, omi orombo were, ewe alupayida diẹ, ẹran ewure, a wa Se lobe, alaisan na yio ma je.

8. Ewe agunmona, ao lo ewe yi dada, eran ewure, epo , iyo, iru, a wa se gbogbo rẹ pọ, alaisan na yi o wa ma jẹ. Bi alaisan yi ko ba le, jeun tẹlẹ, ọbẹ yi o si je ki o ma je onjẹ daadaa

9. Odidi aparo, atare odidi 3, a o ko gbogbo rẹ pọ, a o pọ mọn ọṣẹ aláìsàn naa yi o maa fi wẹ

10. Abeyo ọgẹdẹ wẹẹrẹ, ewe ẹru, eru awola, alubosa elewe, egbo ope, egbo ako ibẹpẹ, ẹtu ibon, a wa gun rẹ po, a gun mo ọṣẹ, awa ma fi we, o dara ko ko enikan.